NIS ní àwọn kò ṣèṣẹ̀ máa fí ìwé irinnà ránṣẹ sí àwọn tó bá fẹ

Aworan ọga agba ileeṣẹ to n ṣeto igbokegbodo awọn to n wọ orilẹ-ede Naijiria Image copyright Channels TV
Àkọlé àwòrán Fi adirési to wu ọ silẹ, ki a fi iwe irinna rẹ ranṣẹ si ẹ

Ileeṣẹ to n ṣeto igbokegbodo awọn to n wọ orilẹ-ede Naijiria ti ṣe alaye nipa fifi iwe irinna ranṣẹ si adirẹsi ti ẹni tó ba fẹ gba iwe naa fi silẹ lọdọ awọn.

Wọn ni iru anfani bẹẹ wa lati fi gba iwe irinna ati pe o ti wa tipẹ ṣugbọn awọn eeyan ko lo anfani ọhun ni.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Sunday James sọ pe awọn ko ṣẹṣẹ maa ṣe bẹẹ amọ awọn eeyan ni ko lo anfani naa.

''Ohun ti wọn ni lati ṣe ni pe ki wọn fi apo iwe kalẹ, eleyi ti wọn kọ adirẹsi wọn si lasiko ti wọn ba n ṣeto ati gba iwe irina wọn.Bi wọn ba ti ṣetan, a o si fi ranṣẹ si wọn.''

O salaye pe o ṣeeṣẹ ki awọn ma ti ma sọ fun awọn eeyan to fẹ wa gba iwe yi pe irufẹ anfaani bayi wa ṣugbọn ni bayi,awọn yoo ma tẹ mọ wọn leti.

James ni ibaṣepọ wa laarin awọn ati ileeṣẹ ifiweranṣẹ ki gbogbo eto naa ba a le lọ deede.

Ki lo ṣẹlẹ sẹyin?

Laipẹ yi ni iṣẹlẹ kan waye nilẹ Gẹẹsi nibi ti ọmọ Naijiria kan ti fi ibinu fọ gilaasi ọkọ ileeṣẹ to n soju Naijiria nilẹ Gẹẹsi.

Image copyright ICIR

Ohun to lo mu iwa bẹẹ wa ni pe wọn ko tete fun oun ni iwe irinna pasipọọti lẹyin ti oun ti kọwe lati gbaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

Iṣẹlẹ yi mu ki ile iṣẹ Naijiria ni London kede pe bẹrẹ lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yi,wọn yoo ma fi iwe irinna ranṣẹ si awọn to ba fi adirẹsi ati apo iwe kalẹ sọdọ awọn.

Gbigba iwe irina Naijiria yala nile ni tabi lẹyin odi a ma mu inira waye fun awọn ara ilu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWidows Day 2019: Mo máa ń sá kiri wá owó ilé ni -Opó

Lọpọ igba,awọn eeyan a maa to fún ọpọlọpọ wakati ki wọn to le ri iwe irinna pasipọọti wọn gba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEbola Virus: ìdí tí Ebola fi ń tàn kálẹ̀