Oyo NURTW: Okùn òfin Makinde ti dí ọ̀nà ìjẹ wa

Alaga ẹgbẹ awakọero nipinlẹ Ọyọ Image copyright @Oyoaffairs

Ẹgbẹ awakọ ero NURTW nipinlẹ Ọyọ, ti figbe bọnu pe ki Gomina Seyi Makinde tu okun ofin to fi de awọn nitori aifararọ eto abo to n ba ipinlẹ Ọyọ finra losu karun ọdun 2019.

Alaga ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Ọyọ, Alhaji Abideen Olajide, ti gbogbo eeyan mọ si Ejiogbe lo n parọwa bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita, pẹlu afikun pe bi gomina Makinde se fofin de isọwọ sisẹ awọn asaaju ẹgbẹ ọlọkọ ero, ti di ọna ijẹ wọn lojumọ.

Bakan naa ni Ejigbe tun nahun kesi Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji Aje Ogungunnisọ Kinni, lati bawọn rawọ ẹbẹ si Makinde pe ko tu okun ofin naa lọrun awsn nitori agba ti ko binu ni ọmọ rẹ n pọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alhaji Ọlajide tun salaye pe awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero ko fa ijangbọn kankan lẹsẹ, tawọn si n gba alaafia laaye lai naani pe ijọba fi ofin de wọn, to si tun fi ọwọ sọya pe alaafia ipinlẹ Ọyọ ko ni yinjẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

Ejiogbe wa gbe osuba kare fun aarẹ ẹgbẹ ọlọkọ ero nilẹ wa, Alhaji Najeem Yaasin fun aayan rẹ lati ri daju pe alaafia jsba pada ninu ẹgbẹ awakọ ero nipinlẹ Ọyọ.