Security Meeting: A fẹ́ àgbékalẹ̀ ọlọ́pàá agbègbè láti pèsè ààbò tó rinlẹ̀

Awọn gomina ẹkun iwọ oorun guusu

Awọn gomina mẹfẹẹfa to n bẹ nilẹ kaarọ-oojiire lo peju-pesẹ lati jiroro, lori eto aabo jakejado awọn ipinlẹ ti wọn n ṣoju fun.

Apero naa waye lọjọ Iṣẹgun ninu gbọngan nla Theophilus Ogunlesi, to n bẹ ladojukọ ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo, UCH nilẹ Ibadan.

Awọn ladelade, loyeloye, aṣoju ijọba, ẹlẹgbẹjẹgbẹ awujọ, ajọ awọn ẹṣọ alabo, to fi mọ awọn akoṣẹmọṣẹ nipa aabo ẹmi ati dukia lo kora jọpọ sibi akanṣe eto naa. Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ifojusun wọn si ni lati fi agbajọwọ wa ojutu si gbogbo awọn ipenja to nii ṣe pẹlu eto aabo ni ẹkun iwọ-oorun guuṣu orilẹede yii.

Ninu ọrọ rẹ, gomina ipinlẹ Ekiti, to tun jẹ alaga apapọ fun igbimọ awọn gomina to n bẹ lorilẹede yii, Ọmọwe Kayọde Fayemi ṣe alaye wi pe, gbogbo orilẹede yii lo n koju ipenija eto aabo.

O ni paapaa julọ nipasẹ wahala awọn ajinigbe, iwa ọdaran ati ijọgbọn awọn Fulani darandaran.

O tẹsiwaju wi pe, yoo nira lati wa ojutu si ipenija eto aabo lai ṣe amulo awọn ẹrọ igbalode.

Fayemi ni lati bii oṣu melo kan sẹyin, ni ọkanọjọkan ipade ti n waye laarin aarẹ orilẹede yii, Mohammadu Buhari ati gbogbo awọn gomina lori eto aabo.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe, ipo ti eto aabo orilẹede yii wa ti di ohun ijaya fun awọn eeyan ilu, ọrọ yii ṣi jẹ ohun to n kọ awọn gomina lominu.

O ni gbogbo ibi ti awọn ba de ni ọpọlọpọ eeyan ti maa n beere alaye lori igbesẹ ti awọn gomina n gbe lati dẹkun ipenija eto aabo.

Fayẹmi ni, ojuṣe awọn gomina ni lati rii daju wi pe eto aabo fi ẹsẹ mulẹ ni awọn ipinlẹ wọn, lai ṣe awawi kankan bi o ti n wu, ki o mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè

Gomina ipinlẹ Ondo, ti o tun jẹ aṣoju fun awọn gomina to n bẹ ni ẹkun Iwo-oorun guusu, Arakunrin Rotimi Akeredolu, naa ba awọn eeyan sọrọ nibi apero naa.

O ni awọn gomina naa nilo ifọwọsowọpọ lai fi ti ẹgbẹ oṣelu kankan ṣe lori eto aabo ilẹ Yoruba.

Akeredolu ni, eto aabo gbọdọ fi ẹsẹ mulẹ lati ẹnu iloro ipinlẹ kan si ikeji ni ẹkun iwọ-oorun guusu.

O tẹsiwaju wipe, awọn ijọba ipinlẹ yoo nilo ajọṣepo awọn eeyan ilu lati le tete wa ojutu si ipenija awọn ajinigbe, ọdaran ati Fulani darandaran.

O ni apero naa pọn dandan, nipasẹ odiwọn awọn ipenija to nii ṣe pẹlu eto aabo lorilẹede yii.

Gomina ipinlẹ Ondo ni, ko si ohunkohun to pọju lati ṣe fun aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ilu.

O ni awọn ọdaran to n da omi alafia ilu ru ko bọwọ fun ipo ti ẹnikẹni wa lawujọ, tabi odiwọn ọrọ ti wọn ni.

Alaye rẹ ni pe, ati olowo ati ọlọrọ, ati ọmọde ati agba lo n foju wina ijinigbe nilẹ Yoruba.

Gomina Akeredolu parọwa si awọn eeyan ilu lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu ijọba ati awọn agbofinro, lati le wa ojutu si awọn ipenija to n ba eto aabo wọya ija.

Bakan naa ni gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko, Dapọ Abiọdun lati ipinlẹ Ogun, Gboyega Oyetọla ipinlẹ Ọṣun ati Ṣeyi Makinde to jẹ olugbalejo awọn akẹgbẹ rẹ naa sọrọ.

Wọn pa ẹnu pọ sọ wi pe, igbogun ti oṣi, ainiṣẹlọwọ, ailanfani si eto ẹkọ ati lilo egbogi oloro n bẹ lara awọn ọna abayọ si ipenija eto aabo.

Wọn ṣe alaye wi pe, awọn aṣoju ijọba nilo ifọwọsowọpọ awọn obi ati awọn adari awujọ ninu igbiyanju wọn, lati wa ojutu si ipenija naa.

Gbogbo awọn gomina naa ni wọn pe fun agbekale ọlọpaa agbegbe si agbegbe, ki eto aabo lee fi ẹsẹ mulẹ bi o ti yẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMo máa n forin mi kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ ni -Hameen

Wọn tẹsiwaju pe, lai si eto aabo to fi ẹsẹ mulẹ, yoo nira lati jẹ anfani eto ọrọ aaje to rọṣọmu, bẹẹ si ni awọn oludokowo ti o le mu idagbasoke ba orilẹede yii yoo maa bẹru lati wọle wa.

Apero naa ni ireti wa wi pe yoo waye fun ọjọ mẹta gbako, gẹgẹ bi awọn gomina naa ṣe pinnu lati tẹlẹ awọn amọran ti o ba ti ibi apero naa jade.