Ìtàn Mánigbàgbé: £100, tíí ṣe ₦42,150 àsìkò yìí, nìjọba fun Taiwo Akinkunmi lówó iṣẹ́ lọ́dún 1959

Alagba Taiwo Akinkunmi Image copyright @abdullarhi

Oniruuru awọn eeyan to lami laaka lo ti jade lorilẹede Naijiria, paapa nilẹ kaarọ Oojire wa, ti ọkọọkan wọn si ti ko ipa to jọju si idagbasoke ati irẹpọ orilẹede yii.

Lootọ ni ọpọ wọn ti re iwalẹ asa, amọ awọn miran si wa loke eepẹ, ti ko si yẹ ka tete gbagbe wọn.

Ọkan lara awọn ọmọ Oodua to gbe ogo iran wa ati orilẹede yii ga, to si n se abẹmi loke eepẹ lọwọlọwọ bayii ni Baba Michael Taiwo Akinkunmi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayefi BBC Yorùba: Bàbá ọmọ, Mọ́ṣúárì, Ọlọ́pàá kẹ́jọ́ rò nípa òkú ọmọ tó pòórá

Ta ba si n sọ itan idagbasoke orilẹede Naijiria, titi de ibi ta de duro yii, ti a ko ba tii ranti Taiwo Akinkunmi, itan wa ko tii kun to, nitori ipa to ko lati ri si ifilọlẹ ilẹ Naijiria pẹlu agbekalẹ asia ilẹ wa to rẹwa, ta n pe ni National Flag.

Gẹgẹ bi a se ka a loju opo itakun agbaye Wikipedia, ọmọ bibi ilu Ibadan ni Akinkunmi, amọ ti ẹkọ funfun rẹ ti inu ikoko dudu jade.

Image copyright @ayoadaniel

Ta ni Michael Taiwo Akinkunmi:

 • Ọjọ Kẹwa osu Karun ọdun 1936 ni Michael taiwo Akinkunmi fori sọlẹ silu Ibadan, ọmọ bibi Ibadan si nii se pẹlu
 • Taiwo, gẹgẹ bi orukọ rẹ ti salaye, jẹ ibeji, oun si ni akọkọ ninu awọn ọmọ meji to wa saye lasiko kannaa, latinu iya kannaa, a ko si gbọ nipa ikeji rẹ, tii se Kẹhinde, titi di oni oloni, o si seese ko ma si laye mọ
 • Taiwo gbe lọdọ baba rẹ titi to fi pe ọmọ ọdun ọdun mẹjọ, ko to di pe isẹ gbe baba rẹ lọ si ẹkun ariwa Naijiria, nibẹ si lo ti bẹrẹ ileẹkọ alakọbẹrẹ rẹ, lẹyin ti baba rẹ fẹyin ti si ni wọn pada wa silẹ Kaarọ Oojire nihin
 • Lẹyin ti wọn pada de, Taiwo Akinkunmi fi orukọ silẹ nile ẹkọ alakọbẹrẹ onitẹbọmi to wa ni adugbo Idikan nilu Ibadan, to si pari lọdun 1949
 • Ọdun 1950 lo lọ sile ẹkọ girama Ibadan Grammar School, to si kẹkọ jade kuro nibẹ lọdun 1955, pẹlu iwe ẹri oniwe mẹwa. Lọgan ti Taiwo Akinkunmi ni iwe ẹri girama, lo gba isẹ labẹ ijọba ẹkun iwọ oorun guusu ilẹ yii ijọun, gẹgẹ bii osisẹ ijọba eleto ọgbin lọgba Secretariat
 • Taiwo sisẹ fun ọdun diẹ, ko to tẹkọ leti lọ silu London lati kọ ẹkọ nipa imọ ẹrọ to nii se pẹlu ina ọba, taa mọ si Electrical Engineering, nile ẹkọ ẹkọsẹ ọwọ ti Norwood Technical College
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢé ẹ̀yin lè ṣe jú àwọn tó f'àmì sí Awọlumatẹ?
 • Ileẹkọ yii ni Taiwo Akinkunmi wa, to fi ri ikede kan ka loju ewe iwe iroyin pe wọn n wa awọn to lee ya aworan asia fun orilẹede Naijiria, to n gbaradi lati gba ominira lọwọ awọn oyinbo aminisin nigba naa, aworan asia Naijiria to ya si ni awọn eebo kan saara si pe o pegede, o fi gbọọrọ jẹka, laarin awọn asia yoku ti awọn miran se lọdun 1958
 • Awọ eweko ati funfun si ni Taiwo Akinkunmi fi se asia Naijiria. Awọ eweko naa duro fun ọrọ aje Naijiria tii se eto ọgbin lasiko igba naa, eyiun ilẹ ti eto ọgbin ti n gbooro, ilẹ to lọra fun ohun ọgbin nigba ti awọ funfun tumọ si alaafia
 • Ọjọ Kinni, osu Kẹwa ọdun 1960 ti Naijiria gba ominira si ni wọn fi asia Naijiria naa lọlẹ fun lilo, tijọba si san ọgọrun pọun (£100) fun Taiwo Akinkunmi, eyi tii se ọrinlerugba ati ẹyọ kan dọla, ($281), ta ba si sọ di Naira, o jẹ ẹgbẹrun lọna mejilelogoji ati aadọjọ naira, (₦ 42,150)
 • Taiwo Akinkunmi pada si orilẹede Naijiria lẹyin ẹkọ rẹ lọdun 1963, to si pada si ẹka isẹ ọgbin to ti kuro tẹlẹ lati maa sisẹ titi di ọdun 1994 to fẹyinti
 • Ọjọ Kọkandinlọgbọn osu Kẹsan ọdun 2014 ni ijọba apapọ fun Taiwo Akinkunmi ni ami ẹyẹ OFR nilu Abuja, lati mọriri ọgbọn inu ati ẹbun atinuda to lo fi gbe asia Naijiria, to jẹ oju ni gbese kalẹ
 • Gẹgẹ bii ẹni ti isẹ ọwọ rẹ wu lori, Taiwo Akinkunmi maa n wọ asọ agbada toke tilẹ to jẹ awọ asia ilẹ Naijiria, eyi to tun ba asa Yoruba to ti wa mu
 • Agbo ile baba Taiwo Akinkunmi to wa ni adugbo Ekotẹdo nilu Ibadan ni baba naa n gbe lẹyin to fẹyin ti lẹnu isẹ ọba tan, ti atijẹun si di ọtọtọ ọran
 • Amọ pẹlu igbe awọn akọroyin, ijọba ipinlẹ Ọyọ, lasiko isejọba Ọtunba Christopher Adebayọ Alao Akala, kọ ile kan fun ni adugbo Ayepe, Academy loju ọna Iwo Road nilu Ibadan
 • Koda, awọ eweko ati funfun, tii se asia ilẹ wa ni wọn fi kun ile ọhun
 • Taiwo Akinkunmi ni iyawo, to si bi ọmọ, ilu abinibi rẹ, Ibadan si lo tẹdo si lọjọ ogbo rẹ titi di oni oloni.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKàyééfì Promo: Ìyá, ọmọ tuntun àti olubi ló wà níbùdó ìgbókùsí, àmọ́ òkú ọmọ di àwátì
Image copyright @noaoyodirect

Niwọn igba to jẹ pe arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ta ba se loni, ọrọ itan ni yoo da bo ba dọla, asia ti Taiwo Akinkunmi se lọdun gbọọrọ sẹyin, naa ni orilẹede Naijiria n lo titi di oni.

Ọpọ iran to n bọ lẹyin, ni yoo si maa ka itan nipa ohun ribiribi ti akinkanju ọmọ Yoruba yii gbe ile aye se.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInternational Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró

Taiwo Akinkunmi ti pe ẹni ọdun mẹtalelọgọrin, eyiun 83 bayii, ti ogbo si ti de si baba. Bi o tilẹ jẹ pe baba yii sa ipa tiẹ fun orilẹede rẹ lasiko to wa ni opepe, ni ẹni ọdun mẹtalelogun,amọ bawo ni orilẹede rẹ se n mọriri rẹ nipa sise itọju rẹ lasiko ti agba de sii yii?