Seyi Makinde: Akọ̀wé ìjba tuntun ni Olubamiwo Adeọsun.

Adebamiwo Adeosun Image copyright Oyo state government

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kede iyansipo ọga agba kan nileesẹ elepo rọbi Shell, gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ Ọyọ.

Oluwarẹ ni Arabinrin Olubamiwo Adeọsun.

Atẹjade kan ti akọwe feto iroyin fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Taiwo Adisa fisita lọjọ Ẹti salaye pe akọsẹmọsẹ nileesẹ elepo Shell ni Adeọsun, eyi ti gomina Makinde ni yoo seranwọ lati kopa ninu minu ayipada rere ba ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa ni iyansipo arabinrin Adeọsun lo wa nibamu pẹlu igbagbọ Gomina Seyi Makinde ninu awọn obinrin ati ikopa wọn ninu eto isejọba.

Atẹjade naa fikun pe, akọsẹmọsẹ apoogun to dantọ ni Adeọsun, to si gba oye imọ ijinlẹ akọkọ nile ẹkọ fasiti Benin lọdun 1990, nigba to gba oye imọ ijinlẹ keji nile ẹkọ fasiti yii kanna lọdun 1997.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKàyééfì Promo: Ìyá, ọmọ tuntun àti olubi ló wà níbùdó ìgbókùsí, àmọ́ òkú ọmọ di àwátì

Adebamiwo Adeọsun jẹ ẹni ọdun mẹtalelogoji, to si jẹ ọmọ ile Matọ nilu Ibadan.