Biodun Fatoyinbo: Mò ń gbé Busola Dakolo lọ ilé ẹjọ́

Biodun Fatoyinbo COZA ati Busola Dakolo

Lẹyin awuyewuye tó tẹle ifòròwanilẹnuwo kan, ninu eyi ti Busola to jẹ iyawo olorin takasufe Timi Dakolo, ti fẹsun ifipabanilopọ kan Alufaa ijọ COZA ni Abuja, Biodun Fatoyinbo, pasitọ naa ti ni oun yoo gba ile ẹjọ lọ lori ọrọ naa.

Fatoyinbo ni, irọ pọnbele ni ẹsun Busola Dakolo, ati wipe yatọ si iṣẹ oun gẹgẹ bii pasitọ, oun ko ba arabinrin naa ni nkankan pọ ni ikọkọ.

Ẹsun naa gba gbogbo ori ayelujara kan lati aarọ ọjọ Ẹti, ṣugbọn Fatoyinbo ni oun ko fipa ba obinrin kankan lo pọ ri.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo naa, Busola ni igba ti oun wa ni ileewe girama, ni oun kọkọ pade Fatoyinbo ni Ilorin, Ipinlẹ Kwara, nigba to ṣẹṣẹ bẹrẹ ijọ COZA.

O sọ ninu ẹsun rẹ ti Y! NaijaTV gbe sita wipe, igba meji ọtọọtọ ni pasitọ naa fipa ba oun lo pọ.

Ṣugbọn Fatoyinbo sọ ninu atẹjade kan to fisita lọjọ Ẹti wipe, Busola ati awọn ẹbi maa n wa si ijọ oun, nigba to kọkọ bẹrẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKàyééfì Promo: Ìyá, ọmọ tuntun àti olubi ló wà níbùdó ìgbókùsí, àmọ́ òkú ọmọ di àwátì

O ni o ya oun lẹnu wipe, pẹlu iru eniyan ti Busola ati ọkọ rẹ jẹ ni awujọ, o ya oun lẹnu wipe, wọn le fi iru ẹsun naa kan oun.

Pasitọ naa ni, oun ti fi ọrọ naa to awọn agbẹjọro oun leti ati wipe, gbogbo awọn eeyan ti wọn ni nkan ṣe pẹlu ẹsun naa, ni wọn yoo foju ba ile ẹjọ.

Related Topics