Libya Explosion: Èèyàn 44 ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn lápapọ̀

Aworan ibudo naa Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ajọ iṣọkan agbaye sọ pe ado oloro naa jabọ latoju ofurufu le ibudo ti eniyan to le ni ọgọrun wa

Ọmọ orilẹede Naijiria mẹsan an lo wa lara awọn to ku sinu ikọlu ado oloro to waye ni ibudo ifiniwọ kan ni Libya.

Abẹwo awọn aṣoju Naijiria si ibudo naa, Tajoura, lẹyin iṣẹlẹ naa to waye l'Ọjọru fihan pe, ọmọ Naijiria mẹsan an lo wa lara eniyan bi i mẹrinlelogoji to ku sinu isẹlẹ naa.

Lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye ni ijọba ati ikọ alatako ti Khalifa Haftar n dari ti n di ẹbi ru ara wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajọ to n mojuto ọrọ to kan awọn ọmọ orilẹede Naijiria nilẹ okeere, sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe, eto ti n lọ lati ko awọn eniyan naa pada si Naijiria ki wọn tun to kagbako iku ojiji.

Bakan naa lo sọ pe oun ṣi n duro de iroyin lori boya awọn ọmọ Naijiria ṣi ku to ku sinu iṣẹlẹ naa.

Ọga Agba ajọ naa, Abike Dabiri-Erewa sọ pe awọn aṣatipo to le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn nijọba Naijiria ti da pada sile.

Ẹwẹ, o ti n polongo fun iwadii ati ijiya fun awọn to ṣe ikọlu naa.

Ikọlu yii waye lẹyin oṣe meji ti ọ̀kan ti kọkọ waye nibi ti ko fi bẹ jina si Tajoure.

Ọpọlọpọ awọn aṣatipo naa lo n wa igbeaye 'idẹrun' lọ silẹ Yuroopu, amọ to bọ si ọwọ awọn ajijagbara ni Libya.

Ajọ iṣọkan agbaye ti sọ pe abọ iwadii ti oun ri gba fihan pe niṣe ni awọn oṣiṣẹ alaabo n yinbọn mọ awọn aṣatipo to n gbiyanju lati sa fun ado oloro.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸtàn ni àwọn ọ̀rẹ́ fi ń tan èèyàn lọ si Libya pé iṣẹ́ gidi wà níbẹ̀