Sara-Jayne King: Ọ̀nà ayé mi dàrú torí òbí mi ta mí nù fún alágbàtọ́

Sara-Jayne King

Ọdun 1980 ni wọn bi Sara-Jayne King silẹ South Afrika, lasiko ti awọn eebo amunisin n dari orilẹede South Afrika, awọ rẹ si jẹ amulu-mọla dudu ati funfun bi o tilẹ jẹ pe iya rẹ jẹ alawọ funfun, idi si ree to fi lọ faa kalẹ fawọn obi alagbatọ ti wọn jẹ alawọ funfun, pe ki wọn fi se ọmọ.

Sugbọn ara Sara ko lelẹ nigba to dagba, to si ri pe awọn alawọ funfun lo wo oun dagba ni ilu ọba, UK, eyi lo mu ko pinnu lati se awari orisun ibi to ti sẹ wa lagbaye, to si mu irin ajo rẹ pọn pada wa si orilẹede South Afrika.

O ti le ni ọdun mẹẹdọgbọn ti Sara ti de orilẹede South Afrika gbẹyin, koda, ọmọ ọsẹ meje lo wa ti wọn fi gbe lọ silu ọba, ti ko si niran ohunkohun nipa orilẹede naa rara, koda igbe aye nilẹ Gẹẹsi gan ko dẹrun, nitori pe kii se alawọ funfun pọnbele, to si n tiraka lati farada igbe aye rẹ nilu Surrey, bẹẹ ni ko lee sọ oun to faa, ti iya rẹ fi kọ silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sara Jayne mọ pe oun ko fi awọ jọ awọn toun n pe ni obi oun, amọ ko wa si ero rẹ rara pe alawọ dudu ni, afi igba ti awọn eeyan ilu Surrey jẹ ki eyi ye, tawọn akẹẹgbẹ rẹ nile iwe si maa n fi irun ori rẹ we waya olowu, oun nikan si ni alawọ dudu to foju ganni ri, lọpọ igba si ni wọn maa n sọ fun pe o da yatọ.

Awọn iwa ẹlẹyamẹya ti Sara foju wina rẹ lati kekere lo jẹ ko gba pe nkan kan wa ti ko dara nipa awọn alawọ dudu. Koda, ni ilu to gbe dagba, Crowhurst, oju awọn alarinkiri ati ẹni ti ko pe ni wọn fi n wo alawọ dudu, ti ileewe rẹ kan si maa n ko ounjẹ jọ fun awọn ọmọ ti ebi n pa lorilẹede Ethiopia.

Sara ni oun tiẹ ranti pe oun maa n ri awọn ọmọde alawọ dudu lori tẹlifisan, ti esinsin maa n kun wọn, ti eruku yoo si bo gbogbo ara wọn, eyi to mu ki oun gba pe awọn eeyan to nilo aanu ati iranwọ lo wa ni Afrika, ti ko si yẹ ki eeyan tilẹ doju kọ wọn. Amọ Sara ni inu oun dun pe oun bọ lọwọ ero buruku yii lati igba ti oun ti de si Afirika.

Ni ọjọ kan to n tun yara mama to jẹ alagbatọ rẹ se nigba to wa lọmọ ọdun mẹtala, lo se alabapade lẹta kan ti iya to bi kọ si mama naa ni ọdun kan sẹyin. Ninu lẹta naa lo ti ri ka pe iya oun ni ajọsepọ pẹlu ọkunrin alawọ dudu kan nigba to ku diẹ, ko se igbeyawo pẹlu ọkọ afẹsọna rẹ to jẹ alawọ funfun.

Osu naa lo fẹra ku, ti ko si lee sọ ẹni to ni oyun, boya alawọ dudu ni abi alawọ funfun to jẹ afẹsọna rẹ. Ofin si ti wa nilẹ lorilẹede South Afrika nigba naa pe, alawọ funfun kankan ko gbọdọ ni ibalopọ pẹlu alawọ dudu, ti ẹlẹya mẹya si wọpọ pupọ lorilẹede naa nigba naa

Nigba to bimọ tan, ọmọ naa funfun lawọ, ti wọn si ro pe alawọ funfun ni, wọn sọ orukọ rẹ ni Karoline, amọ nigba ti yoo fi pe osu mẹta, akara tu sepo pe adulawọ ni ọmọ naa, to si jẹwọ fun ọkọ rẹ pe oun se asemase ni. Ọna lati daabo bo iya Sara lo mu ki oun ati ọkọ rẹ dete pe Karoline n se aisan, to si nilo itọju gidi nilu ọba.

Idi ree ti wọn se gbe Sara kuro ni South Afrika lọmọ osu meje, ti wọn si gbe fun alagbatọ nilu ọba, ẹni to ti orukọ Karoline pada si Sara, ngba ti awọn obi Sara si pada de si South Afrika, ni wọn kede pe Karoline, ọmọ wọn ti ku.

Irẹwẹsi ọkan ba Sara pe iya to bi oun mọọmọ kọ oun silẹ ni, to si jẹ ibanujẹ nla fun, amọ ko pẹ lo wọ ile ẹkọ fasiti Greenwich, lati kẹkọ gboye akọkọ lẹka imọ nipa ofin, Law. Asiko yii ni Sara lanfaani lati kọwe si iya to bi, ti onitọun si fesi pe oun yoo dahun awọn ibeere to ba fẹ bi oun amọ ko wu oun lati ni ajọsepọ kankan bi tii wu ko mọ pẹlu ọmọ naa rara, koda, ko kari bọnu lati sọrọ yii.

Idi ree ti Sara se bẹrẹ si ni banujẹ, to si n roun. O bẹrẹ ọti mimu, to si n mu oogun oloro Codeine. Sugbọn ori baa se, iwa palapala yii ko se idiwọ fun ẹkọ rẹ, o gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ati ikeji, to si tun ri isẹ gidi lorisirisi lati se, bẹẹ lo di akọsẹmọsẹ agbohunsafẹfẹ lori redio, Amọ oogun oloro to n mu yii lo papa le lẹnu isẹ nigba ti iwa rẹ ko ba taye mu.

Ọna lati wa ibudo ti yoo ti gba itọju, eyi ti owo rẹ ko wọn lo gbe pada si orilede South Afrika, to si ri iwosan nibẹ. O se alabapade ọmọkunrin ti iya rẹ bi lẹyin rẹ, ti wọn si di ẹbi

Afẹfẹ orilẹede naa ba lara mu, ko mu oogun oloro mọ, o ri isẹ gidi, ti Sara si pada di ọmọluabi lawujọ. Nibẹ naa si lo yi orukọ rẹ pada si Karoline Kings ti wọn sọ lọjọ to dele aye, eyi si lo sọ pada di ọmọ orilẹede South Afrika tootọ lẹyin ọpọlọpọ ọdun.

Karoline bẹrẹ isẹ pada lori redio, to si kọ iwe nipa igbe aye rẹ laarin ọdun meji to de si orilẹede South Afrika. O gba ọtẹlẹmuyẹ aladani kan lati ba se awari baba to bi lọmọ lai se aseyọri. Amọ nigba to n polowo iwe rẹ lori redio lasiko to n se eto, o darukọ ara rẹ, ti baba rẹ si pe lẹyin ọjọ kẹta, ti wọn si sọrọ fun ọgbọn isẹju.

Lẹyin o rẹyin, baba ati ọmọ foju kan ara wọn fun igba akọkọ, wọn bu sẹkun, ọjọ yii si ni Karoline ri ara rẹ bii ọmọ eeyan kan, ti inu mi si dun pe mo jẹ alawọ dudu.