Cerebral Palsy: àrùn tó n gba omijé lójú ẹni láìnídìí

Cerebral Palsy: àrùn tó n gba omijé lójú ẹni láìnídìí

Odun 2016 ni wọn ni mo tun ni arun jẹjẹre mọ cerebral palsy mi -Steph

Oriṣiiriṣii àrùn lo n yọ ẹda lẹnu ti ko jẹ ki eniyan le ṣe ohun to wuu ni ọpọ igba.

Steph Hermmerman jẹ obinrin akna da ẹda kan to kọ lati jẹ ki arun de oun mọlẹ.

Arun 'Cerebral Palsy' ti Stpeh ni jẹ ki awọn oniṣegun oyinbo sọ pe ko ni le sọrọ, rin, kọwe tabi ka iwe ni aye rẹ.

Steph ni gbogbo nkan ti awọn dokita ni oun ko le ṣe ni oun pada wa le ṣẹ nitori oun pinnu lọkan oun.

O ni koda lọdun 2016 ti wọn tun ni oun ni arun jẹjẹrẹ ni oun tun fi ṣe ohun gbogbo to yẹ ṣugbọn oun bori gbogbo rẹ.