AfCFTA:Ohun tí Nàìjíríà gbọ́dọ̀ ṣé láti jẹ adùn àdéhùn okòwò kan nàà ní Afrika

Aarẹ Buhari lasiko to n fi ọwọ si adehun naa Image copyright Babangida Yaya Jarmari
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ti kọkọ sọ pe nilo akoko lati fi ikun lu ikun, gba imọran ni orilẹede oun.

Lẹ́yìn ìgbaniníyànjú lóríṣiirisii, Aarẹ Mohammadu Buhari tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn ibúdó olókowò kan fún ilẹ̀ Afrika.

Ohun ti yoo mu anfani pupọ wa ni bi Aarẹ Naijiria Muhamadu Buhari ti ṣe fi ọwọ si adehun okoowo kan naa nibi ipade apero ajọ iṣọkan ilẹ Afrika to waye ni Niger lọjọ Aiku.

Amọ ṣa ki o to le jẹ awọn anfani wọn yi, awọn nkankan wa ti o gbọdo ṣe.

Eyi ni ero adari ile iṣe idokowo nipinlẹ Eko, Muda Yusuf nigba ti o n woye nipa bi aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe buwọlu adehun okowo kan naa ni Afrika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCerebral Palsy: àrùn tó n gba omijé lójú ẹni láìnídìí

Yusuf ni igbesẹ yi yoo ṣina oko owo nipasẹ tita ọja tawọn ile iṣẹ Naijiria n ṣe lawọn orile-ede miran.

Yusuf niiwe adehun yi yoo papa mu ki eto ọrọ aje Naijiria di eleyi ti yoo darapọ mọ tawọn orile-ede miran.

Koda o ni anfani miran tun wa.

Aarẹ Muhammadu Buhari ati Aarẹ Patrice Talon ti Benin, ni wọn fi ọwọ si iwe adehun naa loju awọn olori orilẹ-ede to ku ni olu ilu Niger, Niamey nibi ti wọn yoo kọ ibudo ọrọ aje naa si.

Adehun okoowo naa, AfCFTA ba idiwọ pade lọdun to kọja nigba ti Naijiria yọ ọwọ kuro ninu rẹ ṣaaju ọjọ to yẹ ko buwọlu u.

Ọpọ awọn oluwoye lo n beere pe ṣe erongba ibudo okoowo ilẹ Afrika ọhun ko ni foriṣanpọn, nigba ti orilẹ-ede Naijiria to ni eto ọrọ aje rẹ tobi ju lọ ni Afrika, to tun jẹ olori ẹkun Afrika yọwọ kuro ninu rẹ.

Aarẹ Buhari sọ nigba naa pe oun ṣi nilo akoko lati fi ikun lu ikun, gba imọran ni orilẹ-ede oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'IBB da Abiola lẹ́yìn tó búra pẹ̀lú Quran'

Ọpọlọpọ anfaani lo wa fun Naijiria ninu adehun naa; ọpọ eniyan ni yoo maa ni anfaani si awọn nkan to ba n ṣe jade kaakiri ilẹ Afrika.

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Naijiria darapo mo olokowo kan nile Adulawo

Pẹlu bi Naijiria ṣe ti wa fi ọwọ si iwe adehun naa, afojusun AfCFTA ni lati mu afikun ba kata-kara laarin awọn orilẹ-ede ilẹ Afrika ti n sun mọ imuṣẹ.

Titi di asiko yii, awọn orilẹ-ede Afrika n ba ilẹ Yuroopu da ọrọ aje pọ ju bi wọn ṣe n ṣe laarin ara wọn lọ.

Ipade tọdun yii ni ẹleẹkejila rẹ ni eyi ti yoo mu ki erongba Agreement Establishing the African Continental Free Trade Area nilẹ Adulawọ ṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria