Wole Soyinka: Kò sí ààyè fún ẹnikẹ́ni láti gba ilẹ̀ ìràn Yorùbá

Image copyright @Olafare
Àkọlé àwòrán O to gẹẹ nilẹ Yoruba, o yẹ ki a mọ ohun to kan

Kò sí ààyè fún ẹnikẹ́ni láti gba ilẹ̀ ìràn Yorùbá -Ọọni Ifẹ̀

Ọrọ awọn Fulani darandaran ati awọn agbebọn ajinigbe laarin wọn gba ipade agbaagba Yoruba.

Eyi lo ṣokunfa ipade Oba Ooni ti Ile Ifẹ, Ooni Adeyeye Eniitan Ogunwusi, Ojaja II pẹlu agba ọjẹ onkọwe agbaye ni, Ojọgbọn Wole Soyinka.

Ni Idi Aba, ni Abẹokuta nipinlẹ Ogun ni Akinlatun ti ilẹ̀ Egba ti gba alejo Arole Oodua nile rẹ fun ọrọ apero omọ eriwo naa.

Arole Oodua ni ko ni ṣeeṣẹ fun Naijiria lati tun koju ogun abẹlẹ bii ti Biafra to kọja lọ.

Wọn gba ijọba to wa lori aleefa lasiko yii lati gbe igbesẹ to yẹ lati jẹ ki alaafia jọba kaakiri Naijiria lẹyẹ o sọka.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOrangun: Èdè àti àṣà Yorùba ní láti jọ wá lójú

Awọn eekan mejeeji ni ọrọ ki awọn kan maa ro pe ìbí ju ìbí lọ ko yẹ ko ṣẹlẹ rara ni Naijiria.

Wọn ni ki ijọba ṣe ohun to yẹ lati dẹkun iwa buruku awọn Fulani darandaran kan atawọn Myetti Allah kan ti wọn ro pe awọn kọja agbara ofin ko too tun di ọrọ Boko haram mọ wa lọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌdún 1940 ni wọ́n ti ń sin ọ̀ọ̀nì ilé Delesolu ní Ìbàdàn

Ṣoyinka ati Arole Oodua ni o n dun awọn gidi pe iṣọkan ati ẹmi irẹpọ to wa ni gbogbo ẹkun Naijiria tẹlẹ ti n di ohun igbagbe.

Wọn gba pe eyi ko ṣẹyin iwa ijẹgaba ti awọn kan fẹ tun maa jẹ le iran to ku lori bii amunisin ni eyi ti ko le ṣeeṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌọ̀ni ilé Ifẹ̀, Ọba Adeyeye Ẹnitan Ogunwusi, Ọ̀jájá Kejì ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbi ọdúnKẹrinlelo

Ojaja II ati Akọgun Iṣara fẹnuko pe ki gbogbo ogidi ọmọ Oodua daabo bo ogun idile rẹ.

Ki onikaluku ja fun ẹtọ rẹ ninu ilẹ iran baba nla rẹ nitori oko kii jẹ ti Baba tọmọ ko ma ni ààlà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌọni ogunwusi bẹrẹ abẹwo si orilẹede Brazil

Awọn akọni mejeeji yii gba awọn ọdọ Naijiria lati ji dide si iṣẹ ati iwa ọmọluwabi to yẹ ki a mọ ọdọ mọ.

Image copyright @olafare
Àkọlé àwòrán Emi gana an ti setan lati fowosopo pelu gbogbo ori ade ki a tun ogo ile Yoruba se
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

Awọn agba ọjẹ mejjeji mẹnuba wahala to maa n jade lati ara ẹlẹyamẹya ati aini irẹpọ lorilẹ-ede ati ni agbegbe kọọkan.

Wọn gba awọn eeyan niyanju lati ni ẹmi ifarada ki Naijiria le tẹsiwaju.

Image copyright @olafare
Àkọlé àwòrán Bi a ba se ni looore, ọpẹ laa da nilẹ Oodua

Ooni ti Ile Ifẹ ati Wole Soyinka ni ki onikaluku ni ẹlẹkunjẹkun ṣe agbekalẹ aato ijọba to faaye gba ifikunlukun ati ijiroro ṣaaju igbesẹ to ba kan ara ilu.

Image copyright @olafare
Àkọlé àwòrán Oro to ba gba aaro ni siso a kii fi ale soo nile Yoruba

Wọn ni o yẹ ki ijọba maa gbiyanju lati gbọ ohun tawọn eniyan wọn ba n sọ ki onikaluku le maa fẹdọ lori oronro sun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCerebral Palsy: àrùn tó n gba omijé lójú ẹni láìnídìí

Ni ipari àwọn mejeeji tun ṣe ileri lati gbiyanju agbara wọn ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn to n wa alaafia ati idagbasoke iran Yoruba ati Naijiria lapapọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àjẹ́, eégún, kí ni wọn ò pè mí tán tórí Vitiligo lára mi'

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí