COZA: Ìlú tí ọdaràn ba tí dẹṣẹ ló yẹ kí wọn tí gbẹ́jọ́ rẹ̀ -Agbẹjọ́rò

Biodun Fatoyinbo àti Busola Dakolo Image copyright @BIODUNFATOYINBO/@BUSOLADAKOLO
Àkọlé àwòrán Pasitọ Biodun Fatoyinbo àti Busola Dakolo

Ọrọ ibi ti wọn yoo ti gbẹjọ ẹsun ifipabanilopo ti wọn fi kan Pasito Biodun Fatoyinbo ti ijọ COZA ko yẹ ki o mu awuyewuye wa.

Eyi ni ero agbẹjọro kan, Mohammed Ghali Alaaya ti o ba ile iṣẹ BBC Yoruba sọrọ lori ọrọ yi.

Laipẹ́ yi ni awọn akojọpọ agbẹjọro kan ati awọn ajafẹtọ-ọmọniyan kan sọ pe awọn ko fẹ ki wọn gbọ ẹjọ naa ni Abuja bi ko ṣe ni Eko ti wọn ti mẹsun naa wa.

Ilu Ilorin nipinlẹ Kwara ni wọn ni Biodun Fatoyinbo ti da ẹsẹ naa ni nnkan bi ogun dun sẹyin amọ lọwọ bayi ilu Abuja lo fi ṣe ibujoko.

Ninu alaye agbẹjọro Ghali Alaaya ti ile iṣẹ agbẹjọro Tafa Ahmed & Co, o ni ''ilu ti ọdaran ba ti da ẹsẹ ti ile ẹjọ to si kaju oṣunwọn lati gbẹjọ naa ba ti wa nibẹ lo jẹ ibi akọkọ ti a ti n gbọ iru ẹjọ bẹẹ.''

O ni: ''Nkan mẹta lo máa n ṣe atọna ibi ti a ti le gbẹjọ ọdaran.Akọkọ ni awọn tọrọ naa kan,iru ẹṣẹ ti wọn gbe lọ si ile ẹjọ ati iru agbara ti ile ẹjọ naa ni lati gbọ iru ẹjọ bẹ''

Ghali sọ pe ti ile ẹjọ to ba lagbara lati gbọ ẹjọ naa ba ti wa ni ilu ti wọn ti da ẹsẹ ti ọdaran naa si n gbe ilu naa,ibẹ ni wọn yoo ti gbẹjọ rẹ.

O tẹsiwaju pe ti ko ba rọrun lati gbọ ẹjọ naa ni ile ẹjọ yi to ri pe ọdaran naa ko gbe ilu ohun,ibi ti o n gbe nibi ti ọrọ kan lati gbọ ẹjọ naa''lopin igba ti ile ẹjọ to ba ka oju osunwọn ba ti wa nibẹ.''

Nipa ọrọ Fatoyinbo to jẹ pe ilu Eko ni wọn ti fẹsun kan an ṣugbọn to n gbe ilu Abuja, Alaaya ni ohun to sunmọ ju pe yoo ṣẹlẹ ni ''ki wọn gbẹjọ naa ni lọ ilu to ba ti dẹsẹ naa''.

''Amọ ti idiwọ ba wa ti ko ni jẹ ki igbẹjọ nibẹ rọrun,ilu ti ọdaran n gbe ni ibi to kan lati gbẹjọ naa.''

O wa fi kun ọrọ rẹ pe o ṣeeṣe lẹyin ti ọrọ naa ba de iwaju adajọ ko jẹ Eko ni wọn yoo ti gbẹjọ naa ṣugbọn ọrọ ku si ọwọ adajọ.