Oxfam: Ìjọba kìí gba owó orí púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn olówó tàbí fìyà jẹ àwọn alájẹbánu

Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìwádìí fihàn wí pé yóò tó ọdún 46 kí ẹni tí ó ní owó jùlọ ní Naijiria fi ná owó rẹ̀ tán, bí ó tiíẹ̀ ń ná owó tó tó mílíọ́nù dọ́là kan ní ojoójúmọ́.

Awọn adari orilẹede ni Iwọ- Oorun Ilẹ Afirika (West Africa), ni ko naani lati ri wi pe ibaradọgba wa laarin awọn olowo ati awọn mẹkunnu ni agbeegbe naa.

Iwadi Oxfam lo gbe e jade bẹẹ wi pe, agbeegbe Iwọ Oorun Ilẹ Afirika lo ni aidọgba to pọ julọ laarin awọn talaka ati olowo julọ ni agbaye.

Ninu iwadii naa, Oxfam ni ida kan awọn ọlọla ni Iwọ Oorun Afirika ni owo ju gbogbo ida mọkandinlọgọrun to jẹ mẹkunnu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ati wi pe yoo to ọdun mẹrindinlaadọta ki ẹni to ni owo julọ ni Naijiria fi na owo rẹ tan, bi o tilẹ n na owo to to miliọnu dọla kan ni ojoojumọ.

Nigeria, Niger, Benin, Sierra Leone ati Guinea Bissau lo fi idirẹmi pẹlu maaki to kere julọ nipa nina owo ara ilu, owo ori ati kara-kata oja lorilẹede wọn.

Gẹgẹbi iwadii naa se gbe e jade, Naijiria lo se ipo kẹrindinlogun ninu awọn orilẹede mẹrindinlogun to wa ni ẹkun Iwọ-Oorun Ilẹ Afirika naa, nigba ti Sierra Leone se ipo mẹẹdogun, ti Niger ati Guinea Bissau se ipo kẹrinla ati mẹtala lọwọọwọ.

Image copyright Getty Images

Ni ẹka ẹnawo, iwadi naa sisọ loju rẹ pe awọn ijọba to wa lẹkun iwọ oorun Afrika lo n se iwuri fun aibaradọgba laarin awọn eeyan wọn nitori pe wọn ko pese owo sita fun ẹka igbe aye ọmọ niyan bii eto ẹkọ ati ilera.

Lori sisan owo ori, iwadi naa ni ijọba kii gba owo ori pupọ lọwọ awọn eeyan to lowo lọwọ atawọn ileesẹ nla nla, bakan naa lo ni wọn kii jẹ awọn eeyan ati ileesẹ to n sa fun owo ori niya bo se yẹ, ka ma sẹsẹ sọ tawọn eeyan to ko owo ilu jẹ.

Oxfam wa salaye pe, ireti si wa ti ijọba orilẹede kọọkan to wa nilẹ Afirika ba lee se awọn atunse ni agbọn kọọkan ti ọrọ yii kan.