Ìwọ́de Shiite: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ogójì ọmọ ẹgbẹ́ Shiite lẹ́yìn ìwọ́de

Ọọfisi awọn asofin ti wọn bajẹ Image copyright @Deadlinechic

Ọwọ sinku awọn ọlọpa ti tẹ ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin Shiite ti wọn n fẹhonu han nile asofin apapọ ilẹ wa nilu Abuja.

Atẹjade kan ti osisẹ alarina ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa, Anjuguri Manzah fisita salaye pe, oun ba imọ awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite naa jẹ lati fi tipa gba akoso ile asofin apapọ ilẹ wa lọjọ Isẹgun.

Atẹjade naa ni iwọde wọọrọwọ lawọn ọmọ Shiite naa fi boju kọrọ to bẹyin yọ, ti wọn si fẹ fi tipa wọ ile asofin apapọ amọ tawọn ọlọpaa to wa nibẹ ko gba fun wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Manza ni idi ree ti wọn fi yinbọn mọ ọlọpaa meji lẹsẹ, ti wọn si tun lo okuta ati ọkọ lati fi da ọgbẹ si ọlọpaa mẹfa lara, ti wọn si ti gbe wọn lọ sile iwosan.

Atẹjade naa ni ọwọ awọn ọlọpaa ti ba ogoji ọmọ ẹgbẹ Shiite ti wọn kopa ninu iwọde naa, ti iwadi si ti n lọ lọwọ.

Image copyright @imnig_org
Àkọlé àwòrán Shiite tún fẹ́ fi ẹ̀hónú hàn lórí 'ọ̀pọ̀' ọmọ ẹgbẹ́ wọn ti iléèṣẹ́ ológun Nàìjíríà pa.

Atẹjade naa wa rọ awọn olugbe ilu Abuja lati maa ba isẹ oojọ wọn lọ, ti alaafia si ti n pada jọba ni agbegbe naa.

Shiite ati ọlọpa fija pẹẹta nilu Abuja

Ẹgbẹ Musulumi Shia ti fẹsun kan awọn ọlọpaa pe, wọn pa eeyan meji to n fẹhọnu han lasiko ti wọn wa se iwọde ni Ile Igbimọ Asofin apapọ ni ilu Abuja.

Eyi waye lẹyin ti ẹgbẹ Shia se ifẹhọnu han lọ si Ile Igbimọ Asofin ni ilu Abuja, eleyii to fa yanpọn-yanrin laaarin Shia ati awọn ẹsọ alaabo Ile Igbimọ Asofin.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn mùsùlùmí Shiite kọlu àwọn ọlọ́pàá lọ́pọ̀ ìgbà nibi tí wọ́n ti ṣe ìwóbi pé k'ìjọba tú olórí wọn sílẹ̀

Iroyin fikun un wi pe, awọn ẹgbẹ Shia to wa se ifẹhọnu han naa le ni ẹgbẹẹrun, ti wọn si koju awọn ọlọpaa, ki o to di wi pe awọn ọlọpaa koju wọn.

Gbogbo ilẹkun to wọ ile igbimọ asofin naa ni wọn ti ti bayii, ti awọn asofin ko si le e jade.

Image copyright Getty Images