Seyi Makinde: Ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tó pọn dandan ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní Ọyọ

Gomina makinde n ba awọn akẹkọ sọrọ Image copyright Seyi Makinde

Ijọba ipinlẹ Ọyọ tun ti tẹnumọ pe ilana oun lati pese ẹkọ ọfẹ to pọn dandan nipinlẹ Ọayọ lawọn ile ẹkọ ijọba si tun n fẹsẹ mulẹ o

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde lo satẹnumọ ọrs yii latinu atẹjade kan ti olori osisẹ sba nipinlẹ Ọyọ, Arabinrin Ọlọlade Agboọla fisita.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni oun ti gbẹsẹ le asa gbigba owo lawọn ileẹkọ alakọbẹrẹ ati girama to jẹ ti ijọba lasiko ti wọn se ibura fun oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa, ti wọn fi sọwọ sawọn akọwe agba ati olori awọn ọọfisi to wa feto ẹkọ yika ipinlẹ naa tun kede pe lati ọjọ ti gomina Seyi Makinde ti di gomina ni owo gbigba lawọn ileẹkọ ijọba ti di eewọ.

Image copyright Seyi Makinde

Atẹjade ọhun fikun pe "Mo fẹ tun tẹnumọ fun yin pe gbigba owo lawọn ile iwe labẹ etekete kankan jakejado ipinlẹ Ọyọ lodi sofin, ẹnikẹni to ba si tapa si asẹ yii laa ri bii abẹyinbẹbọjẹ, ijiya to jopin si n duro de onitọun."