Ajínigbé: Afurasi Ajínigbé jí ọmọkùnrin kan gbé ní Ibadan, ọwọ́ tẹ̀ẹ́ ní Eko

Ọmọkunrin ti wọn ji gbe

Ẹnu ko gba iroyin ni deede aago meje alẹ ọjọ Isẹgun ni adugbo Ikoyi nilu Eko, nigba ti ọwọ palaba ọkunrin afurasi kan, ti a ko mọ orukọ rẹ, segi.

Ọkunrin naa, lawọn ọkọ ọlọpa kan sadede da duro lẹba titi, ti wọn si wọ bọ silẹ ninu ọkọ rẹ.

Ọmọdekunrin kan ti ko ju ọmọ ọdun mẹwa lọ, to wa lẹyin ọkọ rẹ, ni wọn ni afurasi naa ji gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A gbọ pe ni kete ti mọto naa de oju titi Ikoyi ni ọmọdekunrin yii figbe ta pe, kawọn eeyan gba oun kalẹ lọwọ ajinigbe.

Eyi lo mu ki obinrin kan tete fi mọto sẹburu ọkọ afurasi ajinigbe naa, ti wọn si da duro pẹlu atilẹyin awọn ọlọpa to wa nitosi ibẹ.

Gbogbo igbiyanju wọn lati fi ọrọ wa afurasi naa lẹnu wo lo ja si pabo, nitori n se lo bẹrẹ si ni se bii ẹni to ni arun ọpọlọ.

Nigba ti a fi ọrọ wa ọmọdekunrin naa, to pe orukọ ara rẹ ni Ahmed Saka lẹnu wo, o ni oun lo n lọ si ẹba opopona marosẹ Ibadan si Eko, ladugbo Guru Maharaji ti mama oun ti n ta ẹran igbẹ ni.

Ahmed ni sadede ni ọkunrin afurasi naa gbe mọto rẹ duro lẹba oun, to si ni ki oun wọle sinu mọto, to si gbe oun wa silu Eko loni.

Ahmed Saka salaye pe aba Agbo, lẹba agbegbe Odumakin ni baba oun n gbe.

O fikun pe, awọn eeyan to wa ninu ọkọ naa to marun tawọn jọ de ilu Eko, amọ awọn yoku ti sọkalẹ, to si ku oun ati ọkunrin afurasi naa.

Ọmọdekunrin naa ni ọkunrin naa n dunkoko mọ oun pe, ti oun ba fi pariwo, oun yoo sọ oun di isu.

Lootọ ni ọpọ isu wa lẹyin mọto ọkunrin naa, amọ a ko lee sọ boya eeyan lo sọ di isu abi bẹẹ kọ, amọ se lo n kigbe pe isu lasan ni wọn, kii se eeyan ni oun sọ di isu,

Awọn ọlọpa to wa ni adugbo Ikoyi ti wa gbe ọkunrin afurasi naa, ati ọmọdekunrin ti wọn lo ji gbe, lọ si agọ wọn.

Ẹkunrẹrẹ iroyin yii ati fidio bi ọrọ naa se waye n bọ lọla, ẹ maa ba wa bọ.