'Tinubu 2023': 'Èmi kọ́ lò rán ẹgbẹ́ 'Asiwaju Reloaded Ambassadors' níṣẹ́ o'

Bola Tinubu Image copyright Twitter/APC
Àkọlé àwòrán Idibo aarẹ ọdun 2023

Asiwaju Bola Tinubu ti fesi si ọrọ to tan kalẹ pe oun dupo aarẹ ọrilẹede Naijiria lọdun 2023.

Tinubu to jẹ ọkan lara awọn olori ẹgbẹ oṣelu APC sọ pe ahesọ ọrọ lasan lawọn eeyan kan n gbe kiri.

Tinubu fọrọ naa lede nigba to kẹyin si awọn ẹgbẹ kan t'orukọ wọn n jẹ "Asiwaju Reloaded Ambassadors.''

Awọn ẹgbẹ ọhun ni wọn wọ aṣọ ti wọn kọ ''Tinubu 2023'' si lara.

Tinubu sọrọ loju opo Twitter rẹ pe oun ko mọ ẹgbẹ naa ri, o ni pe wọn n ṣe ohun to wu wọn nitori oun ko ran wọn niṣẹ.