Ilé aṣòfin àgbà: Ìsìnmi olóṣù méjì wa kò le è ṣàkóbá fún àyẹ̀wò mínísítà

Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright @Bashirahmaad

Aarẹ ile asofin agba, Ahmad Lawan ti kede pe, aarẹ Muhammadu Buhari yoo gbe orukọ awọn eeyan to fẹ yan sipo minisita wa siwaju ile asofin agba lati sagbeyẹwo wọn ki ọsẹ yii to pari.

Lasiko ijoko ile to waye lọjọru ni Lawan kede igbesẹ yii.

Aarẹ ile asofin agba salaye pe, ijọba apapọ n sisẹ kara lori akọsilẹ orukọ awọn eeyan to fẹ gba ipo minisita naa lọna ati ri daju pe awọn eeyan ti musemuse wọn da musemuse ni wọn yan lati sisẹ sin orilẹede yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ti le ni osu kan bayii ti aarẹ Buhari ti sebura fun saa keji sugbọn ti ko ti kede awọn minisita ti yoo wa ninu ijọba rẹ.

Eyi si lo mu ki Senetọ Bassey Akpan fi pe akiyesi awọn akẹẹgbẹ rẹ lasiko ijoko ile naa pe, isẹlẹ ọhun se apakan jamọ, nitori pe awọn asofin naa yoo lọ fun isinmi olosu meji laipẹ.

Akpan ni bi aarẹ se fi iyansipo awọn minisita naa falẹ yoo se akoba fun eto ayẹwo ati fifi ontẹ lu wọn, eyi ti ile asofin agba fẹ se fun wọn.

Image copyright @NationalAssembly

Nigba to n fesi lori akiyesi yii, Lawan fọwọ sọya fawọn akẹẹgbẹ rẹ atawọn ọmọ Naijiria pe, aarẹ Buhari ko ni pẹ fi orukọ naa sọwọ, eyiun ki ọsẹ yii to pari.

O ni ti awọn asofin agba naa yoo si se ayẹwo fun awọn to fẹ gba ipo minisita ọhun, ko to di pe wọn lọ fun isinmi olosu meji eyiti yoo bẹrẹ lọjọ Kẹrindinlọgbọn osu Keje taa wa yii.