NGARSA: Ọmọ Nàìjíríà ń retí ifẹ ẹ̀yẹ lọ́dọ̀ yín - Aarẹ́ Buhari

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀríyá ò lópin láti ìgbà tí Nàìjíríà ti júwe ilé fún South Africa

Ni Naijiria ati lorilẹede Egypt ni gbogbo awọn ọmọ Naijiria ti n fi idunu han si bi Super Eagles ṣe da sẹria iya fun Bafana Bafana.

Kete ti ifẹsẹwọnsẹ naa pari ni ariya ti bẹ sode lorilẹede Egypt laarin awọn ọmọ Naijiria to wa nibẹ.

Bakan naa ni ọrọ ikini n jẹyọ lọtun losi latọdọ awọn ọmọ Naijiria lati dupẹ lọwọ ikọ Super Eagles ati lati fi anfani naa sọ ireti wọn.

Aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari ti pẹlu awọn ọmọ Naijiria lati fi ikini ku orire ranṣẹ si ikọ Super Eagles lori bi wọn ṣe bori ikọ South Africa ninu idije AFCON.

Ami ayo si ọkan ni Naijiria fi ṣagba akẹgbẹ wọn lati tẹsiwaju lọ abala to kangun si aṣekagba.

Image copyright Ahmad Bashir
Àkọlé àwòrán Aworan Aarẹ Buhari ati ikọ Super Eagles ki wọn to gbera lọ ife ẹyẹ agbaye Russia 2018

Aarẹ Buhari ninu ọrọ to fi sita loju opo Twitter sọ pe ohun iwuri lo jẹ ti ikọ naa si ṣe afihan ifarajin ati ọkan akin eleyi ti a mọ Naijiria si.

O ni gbogbo ọmọ Naijiria lo n reti ki wọn gbe ife ẹyẹ AFCON wa si ile.

Yatọ si ikini ti aarẹ, awọn ọmọ Naijiria naa n gbe oṣuba kare fun ikọ Super Eagles.

Ninu ọrọ wọn, wọn kan sara si agbabọọlu Naijiria Chukwueze to fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Pẹlu abajade yii, Naijiria ti tẹsiwaju lati kopa ninu abala to kangun si aṣekagba idije AFCON 2019.

Ọkan ninu Algeria tabi Ivory Coast ni wọn yoo ba pade ninu ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye lọjọ kẹrinla oṣu yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAFCON 2019: Ọmọ Nàijíríà rọ Super Eagles lati tubọ sápa wọn pẹlú Madagascar