Poly Ibadan: Lóòtọ́ ni a dáná sún fóònù àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe màgòmágó nínú ìdánwò

Aworan ami idanimọ Poly Ibadan atiafihan ina to n jo Image copyright polyibadan
Àkọlé àwòrán Ile ẹkọ gbogboniṣe Poly Ibadan ni ofin ileewe ko fayegba ki akẹkọ gbe ẹrọ ibanisọrọ wọ yara idanwo

Ko si irọ nibẹ, a dana sun foonu awọn akẹkọ wa ti wọn tapa si ofin pe ki wọn ma ṣe gbe ẹrọ alagbeka wọ inu yara idanwo.

Agbẹnusọ ile ẹkọ gbogboniṣe ti a mọ si Poly Ilu Ibadan, Ọgbẹni Soladoye Adewole lo lede ọrọ yii fun ile iṣẹ Iroyin BBC Yoruba.

Adewole ni awọn ko ṣẹsẹ fi ikilọ sita fawọn akẹkọ lati ma ṣe gbe ẹrọ ibanisọrọ wọ yara idanwo mọ.

''Lati le jẹ ki wọn mọ pe a ko mu ọrọ naa bi awada lo jẹ ki a gbe igbeṣẹ yii, lootọ la dana sun awọn ẹrọ alagbeka ti a gba lọwọ wọn''

Iwa makaruru lasiko idanwo jẹ ipenija to n ba ẹka eto ẹkọ lorileede Naijiria jẹ ti awọn adari eto ẹkọ a si maa wa orisirisi ọna lati dẹkun rẹ.

Jijo foonu awọn akẹkọ yii ni ina jẹ ọna kan ti o mu iriwisi ọtọọtọ wa paapa julọ ti a ba ro iye owo ti wọn fi ra awọn foonu wọn yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti BBC Yoruba beere lọwọ ọgbẹni Adewole pe ṣe biba awọn foonu naa jẹ ko ni da bi iwa basejẹ lati ọdọ ile ẹkọ naa, o sọ pe:

''Bi eeyan ba fi owo iyebiye ra nnkan ti yoo ṣe ipalara f'awujọ, ṣe a ma ni tori bẹẹ a ko ni gba a lọwọ rẹ tabi ki a baa jẹ ki o to le ṣe ipalara f'awujọ?''

O salaye pe ''ninu awọn akẹkọ wọn yi ni awọn ti yoo jẹ adari awujọ lọjọ iwaju yoo ti jade, ti a ko ba dẹkun iwa ibajẹ fun wọn nisinyii, kini ka ti wi ti o ba di ni ọla?''

Lọjọru ni awọn alaṣẹ Poly Ibadan da ina sun awọn foonu alagbeka ti iye owo wọn to miliọnu naira. Awọn aṣoju akẹkọọ ile iwe naa ati awọn akọroyin lo peju si ibi ti wọn ti dana sun awọn foonu wọnyi.