SERAP: Àwọn èèyàn Oyo gbọdọ̀ dásí àbá àjọ tó ń gbógun tìwà ìbàjẹ́

Seyi Makinde Image copyright Facebook/Seyi makinde

Ajọ SERAP ti rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati sọ tẹnu wọn lori aba lati da ajọ to n gbogun tiwa ajẹbanu nipinlẹ naa silẹ.

Ọjọru ni Gomina Seyi Makinde gbe aba ọhun lọ siwaju ile igbimọ aṣofin lati ṣiṣẹ lori rẹ.

Igbakeji adari ajọ SERAP, Ọgbẹni Kola Oluwadare to ba BBC Yoruba sọrọ, rọ awọn ara ilu lati lọ sọ tẹnu wọn nigba ti awọn aṣofin ipinlẹ Oyo ba n gbe aba naa yẹwo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni, o ṣe pataki ki awọn ọmọ ipinlẹ Oyo kopa gboogi ninu eto ati sọ aba naa dofin, ki wọn le sọ ohun ti wọn fẹ ko wa ninu ofin naa.

Ọgbẹni Oluwadare ni, eyi ko ni fun gomina lagbara lati fi ajọ naa dunkoko mọ awọn ẹgbẹ alatako ijọba rẹ.

Ẹwẹ, Gomina Makinde ṣalaye pe, igbogun tiwa ibajẹ yoo fawọn oludokowo ni igboya lati da okoowo silẹ nipinlẹ Oyo.

Koda Gomina fikun ọrọ re pe, oun ṣetan lati lọ jẹjọ niwaju ajọ to n gbogun tiwa ajẹbanu ti ẹnikẹni ba f'ẹsun iwa ibajẹ kan oun.