Ìtàn Mánigbàgbé: Òwe ‘aṣọ kò bá Ọ́mọ́yẹ mọ́... kọ́ wa láti máa ní ṣùúrù

Obinrin were to wa ninu ahamọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn baba nla wa nilẹ Yoruba jẹ ọlọpọlọ pipe, ti ori wọn kun fun ọgbọn ati oye.Oniruuru nlkan si ni wọn fi maa n se akawe ọrọ bii owe, akanlo ede, afiwe ati awọn isẹlẹ miran to kọ ni lọgbọn.

Ọkan ninu awọn isẹlẹ to kọ ni lọgbọn, ti wọn sọ di owe, to si di ohun manigbagbe ni itan kan to nii se pẹlu Ọmọyẹ ati ọmọ iya rẹ.

Itan naa si lo di owe, ti wọn fi n sọ pe "Asọ ko ba Ọmọyẹ mọ, Ọmọyẹ ti rin ihoho wọja."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Niwọn igba to jẹ pe bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba, tii se baba itan, itan Ọmọyẹ yii lo ni ọpọ ọgbọ ati oye ninu, paapa fun itọni awọn ọdọ iwoyi, ti ko si yẹ ka ma mọ itumọ owe naa.

Àkọlé fídíò,

'Àwa táa jẹ́ alágbàtọ̀ gan, èèyàn ni wá, ẹ ye ṣe wa bí ẹranko'

Bi itan naa se lọ ree:

Obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Iyalufa lo n gbe ni ilu kan laye atijọ, eyi ti wọn n pe ni Ijaye, obinrin yii ati ọkọ rẹ ti pinya nitori aawọ ti ko ni ojutu, ti onitọun si ti fẹ iyawo miran si agbegbe Ibarapa, ti Iyalufa si n da gbe pẹlu awọn ọmọ rẹ.

Àkọlé fídíò,

Wo ọmọ tó kọ̀ láti sin òkú ìyá rẹ̀ fún ọdún mẹ́wàá àti ìdí tó fi kọ̀ bẹ́ẹ̀

Iyalufa bi ọmọbinrin meji, ọkan n jẹ Ọmọyẹni nigba ti ekeji si n jẹ Ọmọlufa, ti wọn mu lati ara orukọ iya rẹ.

Ọmọyẹni lo jẹ aburo fun Ọmọlufa, agba naa kii si se agba kan to pẹ lọ titi, tori ọdun meji pere ni wọn gba lọwọ ara wọn.

Àkọlé fídíò,

Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Gẹgẹ bii obinrin to n da gbe, Iyalufa n ko ba oju, to si n ko ba imu lati ri daju pe ile aye dun gbe fawọn ọmọ rẹ mejeeji.

O fẹ ki wọn lee jẹ oloriire lọjọ ọla, sugbọn gbogbo aayan obinrin yii lo so eso rere lori Ọmọlufa, to si ja si pabo lori Ọmọyẹni.

Ọmọlufa jẹ onirẹlẹ obinrin, o ni itẹriba, to si maa n gba imọran iya rẹ amọ onijagidi jagan ẹda, olori kunkun, alailẹkọ ati onipanle eniyan ni aburo rẹ, to n jẹ Ọmọyẹni, eyi ti apekuru rẹ n jẹ Ọmọyẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọmọyẹni lo jẹ aburo fun Ọmọlufa, agba naa kii si se agba kan to pẹ lọ titi, tori ọdun meji pere ni wọn gba lọwọ ara wọn.

Bi ọjọ ti n gori ọjọ, ti oṣu n gori oṣu, awọn ọmọbinrin mejeeji yii n dagba, wọn n to oju bọ, ti wọn si to ẹni to n yan isẹ ati okoowo ti wọn yoo se laayo.

Ọmọlufa yan iṣẹ agbẹ laayo, to si di agbẹ paraku, to ni oko nla, ti kii si ṣe imẹlẹ, ọwọ rẹ ji sowo, iṣu rẹ n ta, agbado rẹ n yọ ọmọ bọkua-bọkua, to si n fi owo, ounjẹ ati aṣọ kẹ iya wọn.

Ṣugbọn Ọmọyẹ, to jẹ aletilapa ọmọ ko kuku yan iṣẹ aayan laayo kan ni pato, ọlẹ, alapa-masisẹ ni, to si n ti ile ọkunrin kan bọ si omiran lai jẹ pe wọn fẹ sile nisu-lọka.

Àkọlé fídíò,

Kayefi BBC Yorùba: Bàbá ọmọ, Mọ́ṣúárì, Ọlọ́pàá kẹ́jọ́ rò nípa òkú ọmọ tó pòórá

Asẹyinwa-aṣẹyinbọ, Ọmọyẹ, to ti balaaga to ẹni ọdun ogun ọdun ri oyun apete he, lo ba loyun oge, kẹtẹkẹtẹ ba ku, ni iso ba pin.

Yoruba ni bi eegun ẹni ba jo re, ori a maa ya atọkun rẹ.

Àkọlé fídíò,

'Ká tó rí irú Akala, ó di "century" míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l'Ogbomoso'

Inu Iyalufa n dun si ọpọ aseyọri Ọmọlufa amọ ibanujẹ nla lo n dori agba rẹ kodo lori ọrọ Ọmọyẹ.

Lẹyin osu mẹsan ti Ọmọyẹ ti fi inu se oyun lai ri ẹni gba lọwọ rẹ, o papa fi ẹyin gbe ọmọ pọn, o ru re, to si tun sọ re.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Yoruba ni bi eegun ẹni ba jo re, ori a maa ya atọkun rẹ.

Gẹgẹ bii aṣa iran Yoruba, Iyalufa n tọ Ọmọyẹ sọna lori awọn ọna ti yoo gba se abiamọ, ti yoo fi tọju ọmọ rẹ bo se yẹ ati awọn eewọ to rọ mọ itọju ọmọ.

Lara awọn eewọ ti Iyalufa ka fun Ọmọyẹ ni pe, iya ko gbọdọ pọn ọmọ rẹ sẹyin, ki ọmọ naa si jabọ lẹyin iya rẹ, bi eyi ba si ri bẹẹ, iya naa gbọdọ sare ni ihoho ọmọluabi wọ inu ọja ni kia-kia,were-were.

Àkọlé fídíò,

Buga Jesse

Bi bẹẹ kọ, ọkọ meje ni yoo ku mọ ọmọ naa lori, eyiun to ba jẹ obinrin, amọ ti ọmọ naa ba jẹ ọkunrin, aya meje ni yoo ku mọ ọmọkunrin naa lori to ba dagba tan.

Iyalufa kan sọ eewọ yii, gẹgẹ bi awọn agba atijọ ti maa n se lati dẹru ba awọn majesin, ki wọn ma ba a hu awọn iwa kan ni, ti Ọmọyẹ ko si mọ pe ẹru lasan ni ọrọ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Inu Iyalufa n dun si ọpọ aseyọri Ọmọlufa amọ ibanujẹ nla lo n dori agba rẹ kodo lori ọrọ Ọmọyẹ.

Wọn ni ọrọ agba bi ko sẹ lowurọ, yoo sẹ lọjọ alẹ.

Nigba to di ọjọ kan, ṣaa deede ni ọja ti Ọmọyẹ fi pọn ọmọ rẹ sẹyin ba tu lojiji laimọ nibi to ti bẹrẹ mọlẹ, to n fọ asọ.

Ọmọ naa jabọ lẹyin Ọmọyẹ, to si fi ori gba ilẹ.

Àkọlé fídíò,

Eba

Ọmọde yii bu sẹkun, ti ẹkun rẹ si gbalẹ. Igbe ẹkun yii ni Iyalufa gbọ ninu ile to wa, to si sare jade lati wa wo ohun to n sẹlẹ si ọmọ naa.

Ọmọyẹ bu sẹkun, to si sọ fun iya rẹ pe Ṣangba ti fọ, ọmọ oun ti jabọ lẹyin oun.

Iya rẹ binu gidigidi si i, to si gba ọmọ naa lọwọ Ọmọyẹ, pe ki oun lọ fi ẹrọ wọ ọ ni gbogbo ara ninu ile, ki ara ma ba a ro ọmọ naa, paapaa ori to fi gbalẹ.

Àkọlé fídíò,

Fulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

Bi Iyalufa ṣe n pẹyinda lati wọnu ile, ni Ọmọyẹ bẹrẹ si ni bọ asọ lara titi to fi wa ni ihooho ọmọluabi, to si ki ere mọlẹ, to n sare lọ sinu ọja to sun mọ adugbo wọn.

Bi Iyalufa ti ri ohun ti Ọmọyẹ se yii, lo ranti eewọ ijọsi ti oun ka fun Ọmọyẹ, ipa to lee ni ati ọna abayọ, ni oun naa ba sare mu iro ti Ọmọyẹ bọ silẹ, to si n sare lee lọ si aarin ọja, toun tọmọ lọwọ.

Àkọlé fídíò,

Sikiru Alabi

Bo ṣe n lo n pariwo pe, "ẹ ba mi mu Ọmọyẹ, ko duro fi aṣọ sara, ẹru lasan ni mo da ba a pẹlu eewọ naa, ẹ jọwọ, ẹ ma jẹ ki Ọmọyẹ rin ihooho wọ ọja."

O pẹ diẹ ki Iyalufa to pade ẹnikan to n ti ọja naa bọ, to si beere pe ṣe o ba oun ri Ọmọyẹ lọna ọja ni ihooho, tori oun fẹ fun un lasọ ti yoo fi bo ihooho rẹ ni.

Àkọlé fídíò,

Murphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé

Onitọhun se haa, to si da Iyalufa lohun pe, "ASỌ KO BA ỌMỌYẸ MỌ, ỌMỌYẸ TI RIN IHOOHO WỌ ỌJA."

Lati ọjọ naa si ni wọn ti maa n fi isẹlẹ yii pa owe fun ohun to ba ti kọja atunṣe, to ti bọwọ sori, ti ko si ni ojutu mọ.

Àkọlé fídíò,

BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Awọn ẹkọ ti owe yii kọ ree:

  • Ka maa fi suuru lo ile aye
  • Ka maa gbọ ibawi, ka si tun gbọrọ sawọn obi wa lẹnu
  • Ka maa maa fi waduwadu gbọ ọrọ tabi gbe ọrọ kalẹ
  • Ka maa maa fi ẹnà ba awọn ọmọ wa sọrọ, ka si maa jẹ ki alaye wa kun
  • Ka mase dẹja ohun ti awọn agba ba pe ni eewọ nitori pe o lewu pupọ.