Lizzy Anjọrin: Ilé tuntun tí mo rà yìí jẹ́ oríire ìyá mi tó jáláìsí

Lizzy Anjọrin Image copyright Lizzy Anjọrin

Ọpọ eeyan lo n dawọ idunnu pẹlu ilumọọka osere ori itage lobinrin, Lizzy Anjọrin ni Ọjọbọ, nigba to kede loju opo Twitter rẹ pe, Ọlọrun se oore ile tuntun nla kan fun oun.

Lizzy, ẹni to n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ile awodamiẹnu naa tun fikun un pe, bi ile naa ko tilẹ to ile idana ẹlomiran, sibẹ oun ki iya oun to ti jade laye ku oriire, pe oun kọ ile naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

Lizzy ni: "Mo kọkọ fẹ fi ile yii pamọ ni ko to di pe mo niran pe, inu osu kẹfa si ikeje ni awọn ile ti mo ba n kọ maa n pari.

Bẹẹ si ni asise ni yoo jẹ fun mi ti n ko ba sọ ẹri oore ti Ọlọrun se fun mi yii fun araye, ki awọn eeyan to ni ọkan rere lee ba mi gbe orukọ Allah ga."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n mu u wa si iranti nipa ọpọ iya to jẹ oun ati mama oun, Lizzy Anjọrin ni osu Kẹfa si Ikeje ọdun ni iya jẹ oun ati iya oun julọ gẹgẹ bii alarinkiri ti ko nile lori.

O fikun un pe mama oun lo kọ oun bi eeyan se lee fi ara pamọ si abẹ ẹru nla lasiko ti ojo ba n rọ lọwọ,.

O sọ bi awọn ṣe maa n so asọ ara awọn papọ, ki iji lile ati ẹkun omi maa ba gbe awọn lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Buhari, Saraki, Dangote, abẹ́ mi ni wọ́n wà'

Lizzy salaye pe, ko si bi awọn se lee sọra to, ori ẹsẹ awọn ni oun ati iya oun yoo sun lori iduro lasiko ti ẹkun omi ba de, tawọn yoo si maa ju ọpọ ohun ti awọn gba lawin danu nitori ilẹ to n yọ lasiko ojo.

Image copyright Lizzy Anjorin

"Oju wa maa n kun fun omije pupọ nigba ti awọn ta jẹ ni gbese ba n fi wa se ẹlẹya, ti wọn si n pe wa ni orukọ buruku.

Ti wọn ba si kọ lati gba wa laaye pe ka ra nkan awin lọwọ wọn, se la maa n lọ he igbin abi eesan. A se e, ta si lọ ta wọn ni ọja ka to lee jẹun"

Gbaju gbaja osere tiata naa tun tẹ siwaju pe osu kẹfa si Ikeje ọdọọdun ni ebi maa n pa oun ati iya oun julọ, ti iya si maa n jẹ awọn ju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Bakan naa lo fikun un pe, osu kẹfa si Ikeje yii naa ni oun bi ọmọ oun ni ilu Jos lai si ibalẹ ọkan rara tabi ri ifẹ yatọ si lati ọdọ iya ọkọ oun, to si n dupẹ lọwọ mama Ijẹbu, eyiun iya rẹ.

Image copyright Lizzy Anjọrin

"Ẹ jẹ ki n danu duro diẹ na, ma tun tẹsiwaju nipa itan igbesi aye mi lọjọ miran, ọjọ re.

Ma maa sọrọ iya mi lọjọ iwaju sugbọn mo dupẹ lọwọ rẹ pe o n rẹrin si mi, mo si mọ riri ọwọ aanu rẹ.

Mo dupẹ pe o jẹ ọrẹ mi tootọ lasiko yii ati titi aye".

Lizzy Anjọrin wa kede pe ile nla ti oun sẹsẹ kọ naa lo wa ni ijọba ibilẹ Eti-ọsa nipinlẹ Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀