Nollywood: Joke Silva ní ọkọ òun ni ìtànsán òòrùn tó ṣe iyebíye

Olu Jacobs ati Joke Silva Image copyright joke silva

Gbaju-gbaja oṣere Nollywood, Olu Jacobs pe ọdun mẹtadinlọgọrin loni, ọjọ Kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2019.

Jacobs ti kopa ninu ọpọlọpọ sinima nilẹ Naijiria ati okeere. Lọdun 2007, o gba ami ẹyẹ Africa Movie Academy Awards.

Bakan naa ni wọn fi ami ẹyẹ Industry Merit Award da a lọla, fun awọn aṣeyọri to ti ṣe gẹgẹ bi oṣere, nibi ayẹyẹ fifunni ni ami ẹyẹ Africa Magic Viewers Choice Awards.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu iṣẹ ikini ku ọdun ti iyawo rẹ, ti oun naa jẹ oṣere, Joke Silva, ran si ọkọ rẹ, o ṣapejuwe Olu Jacobs gẹgẹ bi itansan oorun to ṣe iyebiye.

O ni Olu Jacobs ni itansan oorun, ologo didan ati aba ọkan oun ninu ifẹ.

Tọkọ-taya yii jọ da ileeṣẹ Lafodo Group silẹ. Ileeṣẹ naa n risi gbigbe sinima jade, o si tun ni ẹka ti wọn ti n kọ nipa iṣẹ sinima ṣiṣe.

Bo tilẹ jẹ wi pe ọpọlọpọ igbeyawo laarin awọn oṣere ni ki i fi bẹ tọjọ ni Naijiria, igbeyawo tọkọ-taya Olu Jacobs ati Joke Silva, jẹ apẹẹrẹ rere.

Image copyright joke silva
Àkọlé àwòrán Igbeyawo Olu Jacobs ati Joke Silva ti pe ọdun mẹtalelọgbọn

Laipẹ yii ni wọn ṣe ajọdun ọdun kẹtalelọgbọn ti wọn ṣegbeyawo.