Afenifere: Àsìkò tó tá tako ìkọlù darandaran nílẹ̀ Yorùbá

Alagba Reuben Fasoranti Image copyright @chimbiko_jerome

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti fiyeni pe awọn afurasi Fulani darandaran kan ti yinbọn pa ọmọbinrin alaga ẹgbẹ Afẹnifẹre, alagba Reuben Fasoranti.

Orukọ oloogbe naa ni Funkẹ Ọlakunrin, tii se ẹni ọdun mejidinlọgọta.

Lasiko to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin salaye pe lootọ ni isẹlẹ naa waye, asiko ti Ọlakunrin n bọ lati ilu Akurẹ si lo se alabapade iku ojiji naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Odumakin salaye pe, obinrin ọhun ati awọn ọmọ ọdọ rẹ ni wọn n bọ lẹnu irinajo naa, asiko ti wọn de ikorita Ọrẹ si lawọn afurasi darandaran yii kọlu wọn, ti wọn si n yinbọn mọ wọn laibikita.

O ni ibọn ba Ọlakunrin ati awọn ọmọ ọdọ rẹ, amọ obinrin naa ni ẹjẹ ko tete da lara rẹ titi to fi gbe ẹmi mi, ti awọn ọmọ ọdọ rẹ si wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

Image copyright Oyo state govt

Odumakin, ẹni ti isẹlẹ naa ba lojiji fikun pe, igba keji ree ti alagba Fasoranti yoo padanu ọmọ rẹ, eyi to ba eeyan ninu jẹ pupọ.

O wa gbarata pe, ilẹ Yoruba yoo dide lati tako ikọlu awọn darandaran yii nitori pe ọrọ naa ti de ojuẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àwa táa jẹ́ alágbàtọ̀ gan, èèyàn ni wá, ẹ ye ṣe wa bí ẹranko'

O ni awọn ikọlu afurasi Fulani ti n legba kan ju ọrin lọ, to si dabi ẹni pe wọn fẹ gbogun ti ilẹ Yoruba ni.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afnifẹre ni agbara ojo awọn darandaran yii ko ni oun ko nile wo, amọ awọn onile ni ko ni gba fun.