MURIC pè fún ìwọ́de lẹ́yìn Jumat láti tako ìgbésẹ̀ ISI lórí Hijab wíwọ̀

Aworan ISI

Ọrọ lori gbigba ibori Hijab lori awọn akẹkọ ileewe girama ISI ni fasiti Ibadan ti fa ọpọ awuyewuye sẹyin.

Amọṣa, titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ọrọ naa ko tii jẹ rodo lọ momi.

Ni bayii, ẹgbẹ kan to n ja fun ẹtọ awọn musulumi, MURIC ti pe fun iwọde lati fi ẹhonu han lori ọrọ naa.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, olori ẹgbẹ MURIC, Ọjọgbọn Ishaq Akintọla ṣalaye pe, gbogbo ọna to tọ lawọn ti gba lati yanju ọrọ naa ni tubinubi, ṣugbọn kaka ki ewe agbọn rẹ dẹ, pipele lo n pele sii.

Ọjọgbọn Ishaq Akintọla ni ẹgbẹ MURIC ti ke sawọn musulumi kaakiri ẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria, lati gunle iwọde alaafia lẹyin isin Jumat ni ọjọ ẹti pẹlu aṣọ funfun lati fi ẹhonu han lori iṣẹlẹ naa.

Image copyright University of Ibadan

O ni ko si awijare fun igbesẹ ti awọn alaṣẹ ileewe girama ISI ni fasiti ilu Ibadan n gbe, labẹ ofin nipa fifofin de elo ibori Hijab ni ileewe naa.

Oloyede ni kaakiri agbaye ni awọn ọmọbinrin ẹlẹsin musulumi ti n lo ibori Hijab sinu imura wọn, ati pe, ọgbọn ati fi ẹtọ ẹkọ dun awọn ọmọbinrin to jẹ ẹlẹsin musulumi ni ileewe naa.

Ni ọdun 2018 ni wahala lori wiwọ ibori Hijab bẹrẹ ni ileewe girama ISI ni fasiti ilu Ibadan, eleyi ti o tilẹ ti de ile ẹjọ pada.