Ọlọwọ: Olùdarí ètò ìṣúná àti àkóso ní Ondo ni Ogunoye tó di Ọlọwọ tuntun

Ọmọọba Ajibade Ogunoye

Ilu Ọwọ ti ni ọba tuntun bayii, orukọ ọba tuntun ti awọn afọbajẹ ilu Ọwọ ṣẹṣẹ dibo yan lọjọ Ẹti ni Ọmọọba Ajibade Ogunoye.

Ogunoye, tii se oludari eto isuna ati akoso nipinlẹ́ Ondo ki wọn to yan sipo naa, ni yoo jẹ Ọlọwọ kejilelọgbọn.

Tilu tifọn ni awọn eeyan ilu Ọwọ fi jade lẹyin ti wọn gbọ ikede orukọ ọba wọn tuntun naa.

Mẹrinla ninu awọn afọbajẹ marundinlogun to wa ni ilu Ọwọ ni wọn dibo fun Ọmọọba Ajibade Ogunoye.

Ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹrin ọdun 2019 ni Ọba ana waja eleyi to ṣilẹkun fun awọn idile oye atawọn ọmọ oye lati du ipo naa.

Related Topics