Afenifere: Ọlọ́pàá kò le sọ bóyá Fulani darandaran ló pa Funke Olakunrin

Alagbà Fasoranti àti ọmọ rẹ̀, Funke Ọlakunrin Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Alagbà Fasoranti àti ọmọ rẹ̀, Funke Ọlakunrin

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Femi Joseph ti fidirẹmulẹ fun BBC Yoruba pe lootọ ni awọn kan ṣekupa ọmọ Alaga fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Reuben Fasoranti, Funke Olakunrin loju ọna Ore si Benin.

Femi Joseph sọ pe ni nkan bi aago meji ọsan ọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu Keje ni iṣẹlẹ naa waye. Ati wi pe oloogbe Olakunrin ni ibọn ba lara awọn eniyan to wa ninu ọkọ meji ti wọn da duro.

Kí ló ń fa awuyewuye nípa ikú ọmọ alága ẹgbẹ́ Afenifere?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

"Nkan ti ileeṣẹ ọlọpaa le sọ ni pe agbebọn ni awọn to ṣe ikọlu naa, nitori pe a ko ti i ni aridaju pe ẹya kan, Fulani darandaran tabi adigunjale ni wọn.''

"Eniyan meje mii ti wọn ji gbe ni a ri doola lanaa loju ẹsẹ ti a de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ti a si n wa ẹnikan to ku lara awọn eero ọkọ keji.

Ọkọ Oloogbe Olakunrin ati ọkọ Toyota Camry kan ti ileeṣẹ akero The Young Shall Grow ni wọn da duro."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

"Ẹlomii ko farapa, awọn ti a doola si ti n ran wa lọwọ pẹlu iwadii iṣẹlẹ naa.

Awọn ti a doola sọ fun wa pe awọn to kọlu wọn to mẹẹdogun niye, ti wọn si gbe ibọn alagbara dani.''

Oriṣiriṣi ariyanjiyan lo ti n waye lori iru eniyan ti awọn to ṣe ikọlu naa jẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Related Topics