Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo kọ̀wé ìbánikẹ́dùn sí aṣíwájú Afẹ́nifẹ́re, Rueben Fáṣọ̀ràntì lórí ikú ọmọ rẹ̀

Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ awọn eekan lo ti n wi tẹnu wọn lori iṣẹlẹ buruku naa

Ibi ọrọ de duro bayii ti fihan pe ipenija abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria nilo amojuto ni kiakia.

Aarẹ orilẹede Naijiria nigbakan ri, Oluṣẹgun Ọbasanjọ lo pariwo sita ninu lẹta ibanikẹdun to kọ ranṣẹ si aṣiwaju ẹgbẹ afẹnifẹre, alagba Rueben Faṣọranti lori ajalu iku ọmọ rẹ obinrin, Funkẹ Ọlakunrin.

Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ koro oju si bi awọn agbebọn kan ṣe pa arabinrin naa to si pe awọn agbofinro nija lori riri awọn to ṣiṣẹ laabi ọhun.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ariwo awọn ajinigbe pawo ni ileeṣẹ ọlọpaa npa lori iṣẹlẹ ọhun ṣugbọn agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin ni rara o, ọwọ awọn darandaran la ba nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo sun ẹkún kíkorò nígbà tí a kí ara wa kẹ́yìn'

Ọbasanjọ sọ ninu lẹta rẹ pe, iṣeku pa arabinrin Olakunrin ba ni ninu jẹ paapaa lasiko yii ti ọpọ awọn aṣiwaju orilẹede Naijiria n pe fun iṣọkan, ikonimọra ninu eto oṣelu orilẹede Naijiria.

Nibayii, aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fawọn oṣiṣẹ alaabo gbogbo lorilẹede Naijiria lati bẹẹrẹ iṣẹ lori ṣiṣawari awọn to yinbọn pa ọmọ alagba Rueben Faṣọranti obinrin lopopona Ondo si Ọrẹ lọjọ Ẹti.

Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, aarẹ Buhari pẹlu tun gbadura itunu fun alagba Faṣọranti.