Àwọn agbébọn jí ìyàwó bàbá Sẹ́nétọ̀ Abbo tó lu obìnrin nílùú Abuja gbé ní Adamawa

Image copyright Nigeria National Assembly
Àkọlé àwòrán Sẹnetọ Abbo sọ fun BBC news Yoruba pe iya oun gan ni wọn kọkọ n beere fun kí wọn to fi ipa ji iyawo baba oun to ṣẹṣẹ bimọ gbe

Ṣe ẹ ranti Sẹnetọ Ishaku Abbo ti fidio fihan laipẹ yii nibi to ti n lu arabinrin kan nile itaja nilu Abuja?

Awọn agbebọn ti pa mọlẹbi rẹ kan; wọn si tun ti ji orogun iya rẹ kan gbe lọ lasiko ti wọn kọlu ilu rẹ nipinlẹ Adamawa lọjọ satide.

Sẹnetọ Abbo ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ile ẹbi oun lagbegbe Muchalla nijọba ibilẹ Mubi North nipinlẹ Adamawa ni nnka bii agogo kan oru.

Sẹnetọ Abbo ṣalaye pe iya oun ni awọn agbebọn naa kọkọ beere lọwọ baba oun nigba ti wọn wọle wa pẹlu ibọn AK47 lọwọ wọn ki awọn aburo oun to sọ fun wọn pe iya oun ti jade laye.

Eyi lo mu ki wọn beere fun iyawo baba oun to ṣẹṣẹ bimọ ni ọsẹ meji sẹyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àwa táa jẹ́ alágbàtọ̀ gan, èèyàn ni wá, ẹ ye ṣe wa bí ẹranko'

Sẹnetọ Abbo ṣalaye siwaju sii pe ni kete tawọn agbebọn naa gunlẹ si agbegbe ọhun, 'taarata ni wọn gba ile awọn lọ nibẹ ni wọn si ti fi ipa ji iyawo baba mi to ṣẹṣẹ bims ni ọjs mọkanla sẹyin gbe lọ tawọn ti ibọn AK 47 lọwọ.'

O tun sọ pe bi wọn ṣe fẹ maa gbe arabinrin naa lọ ni aburo baba sẹnetọ Abbo jade sita to si pariwo lẹyin to ri awọn agbebọn naa. Lẹsẹkẹsẹ lawọn agbebọn naa si yin in nibọn.

Bakan naa la gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ran awọn ikọ kogberegbe ọga ọlọpaa tẹlẹ wọn.