Fasoranti: Wọn ní kí Buhari kìlọ̀ fáwọn darandaran tó n tẹ Yorùbá lójú mọ́lẹ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́...

Ọọni Adeyẹye Ogunwusi Image copyright Ooni of ife
Àkọlé àwòrán Ọọni Adeyẹye Ogunwusi ati Iba Gani Adams ni Yoruba lee gbe igbesẹ to le da iṣọkan Naijiria laamu bi ijọba ko ba tete gbe igbesẹ to tọ

Ọọni ile ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja II pẹlu Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti fariga lori iku ọmọ alagba Rueben Faṣọranti, Funkẹ Olukunrin.

Obinrinn yii ni wọn ni awọn agbebọn ti awọn eeyan fura si pe o ṣeeṣe ko jẹ darandarn fulani yinbọn pa ni ọjọ Ẹti.

Ọọni ile Ifẹ ati Aarẹ ana kakanfo ilẹ Yoruba ni asiko to fun ilẹ Yoruba lati kilọ fun awọn agbenipa darandaran lati maṣe ta ẹsẹ agẹẹrẹ ni aala ilẹ Yoruba mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌgbárùn ni ètò BB Naija kíì ṣe ìgbádùn - MURIC

Ninu atẹjade ti awọn mejeeji fi sita lọjọ Abamẹta lori iṣẹlẹ iku ọmọ aṣiwaju ẹgbẹ Afẹnifẹre naa ni wọn ti fi ibanujẹ wọn han.

Ninu atẹjade tirẹ, Ọọni Adeyẹye Ogunwusi ti ile Ifẹ kilọ fun ijọba apapọ lati tete wa wọrọkọ fi ṣada lori gulegule awọn darandaran Fulani ti wọn n da omi alaafia ilẹ Yoruba ru lọwọ yii.

"Ojuṣe ijọba ni lati daabo bo araalu. Pẹlu ohun to n ṣẹlẹ si wa ni ilẹ Yoruba bayii, bi ijọba ko ba tete wa nnkan ṣe si, afaimọ ki awọn eeyan wa maa bẹrẹ si ni da ọgbọn ati daabo bo ara wọn o, eleyii ti ko ni so eso rere fun iṣọkan orilẹ-ede yii."

Ninu atẹjade tirẹ, Iba Gani Adams ni gbọnmọgbọnmọ awọn "Fulani to n ya wọ ilẹ Yoruba lati ṣe iṣẹ ibi bayii" n fẹ amojuto gidgidi.

O ni iran Yoruba kii ṣe ẹṣin inu iwe ti ko lee ta o, o kan n fẹ ki agbaye mọ awọn to tẹ ọka rẹ niru naa ni ki ọka to ja pada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Á rọ̀ wá lọ́rún tí wọ́n bá lè ṣí ibodè Lekki lọ̀fẹ̀ẹ́ láàrọ̀'

"O yẹ ko ye wọn pe eṣinṣin wọn n jẹ elegbo bayii ni imura silẹ fun igba ti elegbo pẹlu yoo yiju pada lati jẹ eṣinṣin"

"Ki ẹnikẹni maa da wa lẹbi o nigba ti a ba bẹrẹ tiwa." Gani Adams lo sọ bẹẹ.

Ati Ọọni Ilẹ Ifẹ, ati Aarẹ Ọna kakanfo, awọn mejeeji wa ki Alagba Rueben Faṣọranti ku atẹmọra ti ọmọ rẹ to jade laye.