EFCC: Ìwádìí iléeṣẹ́ Alpha Beta Consulting Ltd ṣì ń tẹ̀síwáju lórí ẹ̀sùn N100b

Patako afinimọna ọfiisi ajọ EFCC kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eeyan kan kọwe ifisun tako Alpha Beta Consulting Limited niwaju ajọ̀ EFCC ṣugbọn ajọ naa ni iwadii ṣi n lọ

Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC ni awọn ṣi n wadii ileeṣẹ Alpha Beta Consulting Limited.

Ile iṣẹ yii ni ọpọ n tọka si gẹgẹ bii ọkan lara awọn ileeṣẹ agba oṣelu, aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu lori ẹsun ṣiṣe owo ni magomago.

Ajọ EFCC kọ loju opo twitter rẹ pe ajọ naa ko kawọ gbera lori iwe ifisun kan to jade pe ọwọ ileeṣẹ Alpha Beta Consulting Limited ko mọ lori ọrọ owo kan ti iye rẹ to ọgọrun un biliọnu Naira (N100bn).

EFCC ni lootọ loun tẹwọ gba iwe ifisun kan lori ileeṣẹ Alpha Beta Consulting Limited, 'sugbọn ẹni to kọwe ifisun naa ko fi idi ẹsun rẹ mulẹ to bi o ti yẹ pẹlu awọn ẹri to duro digbi.

"EFCC kii ṣiṣẹ lori ahesọ ọrọ bikoṣe arigbamu ẹri. Ajọ yii ko ni dẹ oju rẹ silẹ ki ẹnikẹni yi orukọ rẹ m'ẹrẹ nitori awọn idi b'adiyẹ da mi loogun maa fọ lẹyin'

EFCC tun tẹsiwaju pe, "...iwadi lori ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ Alpha Beta Consulting Limited ṣi n tẹsiwaju. A ko ni ohunkohun lati fi pamọ."

Iwe iroyin abẹle kan lorilẹ-ede Naijiria lo tẹ iroyin kan sita lọjọ Satide ninu eyi ti o ti darukọ igbakeji aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo pe ọwọ rẹ wa nibẹ.