Fasoranti: Osinbajo ìṣẹ̀lẹ̀ ààbò tó mẹ́hẹ kò mọ níbì kan, káàkiri Nàìjíríà ni

Osinbajo n buwolu iwe ibanikẹdun nile alagba Fasoranti
Àkọlé àwòrán O ni ijọba n sa ipa rẹ lati da abo to jọju pada sorilẹede Naijiria

Lẹyin ti iroyin iku ọmọ rẹ, Funkẹ aya Olakunrin lu si eti araye ni ọjọ Ẹti, ẹsẹ ko gbero ni ile agba ilẹ Yoruba, Alagba Rueben Faṣọranti lati ba a kẹdun.

Iye awọn eekan to ti lọ baa kẹdun tun le ọkan sii ni owurọ ọjọ Aiku nigba ti igbakeji aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajọ pẹlu fi ẹsẹ kan de ile rẹ ni ilu Akurẹ.

Nibẹ lo si ti ṣe ileri pe ijọba apapọ ko ni sun, bẹẹ ni ko ni wo titi ti yoo fi rẹyin ipenija aabo to mẹhẹ eleyi to n doju kọ orilẹ-ede Naijiria bayii.

O ni lara igbesẹ ti ijọba apapọ fẹ gbe naa ni lati ko awọn ologun si oju popo marosẹ kaakiri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀

Lẹyin to ki alagba Rueben Faṣọranti tan ni Igbakeji aarẹ Yẹmi Oṣinbajo to kọwọrin lọ sibẹ pẹlu gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

O ṣalaye pe ọrọ ipenija aabo to mẹhẹ ko mọ si ẹkun kan lorilẹ-ede Naijiria, kaakiri orilẹ-ede yii lo ti n waye.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, "ẹnu mi ko gba ọrọ bayii bi ko ṣe lati ba baba daro. Ṣugbọn ẹ jẹ ki n tun sọ fun yin pe gbogbo awọn oniṣẹ ibi to ṣe iṣẹ yii ni ọwọ yoo tẹ, bẹẹni a n sa gbogbo ipa wa lati daabo bo ẹmi awọn ọmọ orilẹede Naijiria".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGọngọ sọ, ẹlẹ́há pàdé àwọn tó lùú ní jìbìtì nílùú Eko lọ́jà Ibadan
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionInternational Day Against Drug Abuse and Trafficking: ìdí ti mo fi ń mu oògùn olóró