Gọngọ sọ, ẹlẹ́há pàdé àwọn tó lùú ní jìbìtì nílùú Eko lọ́jà Ibadan
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gọngọ sọ, ẹlẹ́há pàdé àwọn tó lùú ní jìbìtì nílùú Eko lọ́jà Ibadan

Gbẹgẹdẹ gbina lọja awọn olohun eelo iranṣọ ni Ogunpa nilu Ibadan nigba ti ẹlẹha kan ṣa deede fi igbe ta to n pariwo "mo ti ri ọ! oo ni lọ!" laarin ọja naa.

Gẹgẹ bii BBC News Yoruba ṣe gbọ, obinrin ẹlẹha yii lọ ra ọja ni ilu Eko ni ọsẹ diẹ sẹyin. Nibẹ ni awọn obinrin meji kan si ti lu u ni jibiti ti wọn si gba owo rẹ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn tun ṣalaye pe bata ni arabinrin yii lọ ra ni ilu Eko ki o to kagbako awọn obinrin meji naa nibi ti wọn ti gbe irin kekere kan lee lọwọ ti wọn si gba ẹgbẹrun lọna ogoji naira lọwọ rẹ.

Ẹlẹha naa to ni wọn lo iṣuju fun oun ni sọ pe lẹyin ti oun kuro ni ọja naa ni oju oun to la lati rii pe gudẹ ni awọn obinrin naa gbe le oun lọwọ dipo bata ti o lọ ra.

Amọṣa, ṣe awọn agba bọ wọn ni ẹni ku ati ẹni nu yoo pade lọjọ kan, ori ti yoo ba arabinrin ẹlẹha yii ṣe lo ni ki o lọ ra ọja ohun eelo aṣọ riran ni ọja Ogunpa ni ilu Ibadan nibẹ ni o ti ṣe kongẹ awọn mejeeji yii.

Gbara ti o kan wa kuu bayii ni ẹlẹha ti figbe bọnu laarin ọja, ti ọkan ninu awọn obinrin mejeeji yi si juba ehoro.

Amọṣa, ọwọ tẹ ọkan ninu wọn, lọgan si ni Ẹlẹha n pariwo, 'ẹ ba mi mu, ẹ maa jẹ ko salọ o!.

Ki a to wi ka to fọ, wọn ti ja arabinrin yi si ihoho pẹlu ọpọlọpọ lilu.

Lẹyin o rẹyin, ẹlẹha ri ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gba pada ninu owo rẹ lọwọ arabinrin ọhun ki wọn to fi silẹ ko maa lọ.