Àwọn olówó Naijiria 5 tí owó wọn ju owó ìsúnná Naijiria lọ!

Àwọn olówó Naijiria Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ìwádìì Oxfam fihàn pé owó àwọn olówó yìí tó 29.9 billion US dola, eléyìí tó ká owó ìṣúná Naijiria fún ọdún 2017.

Olowo marun un lorilẹ-ede Naijiria ni owo to to san owo isunna lorilẹ-ede Naijiria.

Iwadii ti ile-isẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Oxfam gbe jade lo fihan wi pe owo awọn olowo yii le ni biliọnu mọkanlelọgbọn owo ilẹ okeere dọla.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Olowo marun un lorilẹ-ede Naijiria ni owo to to san owo isunna lorilẹ-ede Naijiria.

Eleyii jẹ iye oju owo fun owo isunna Naijiria ni ọdun 2017, triliọnu meje naira o le ni o ma a jẹ iye owo Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFasoranti: Dẹ́rẹ́bà tó wa ọmọ Fasoranti ṣàlàyé bí wọ́n ṣe pa Funke Olakunrin

Orukọ awọn marun un ti iwe iroyin Forbes gbe jade pe wọn ni owo julọ ni orilẹ-ede Naijiria ni:

  • Aliko Dangote
  • Mike Adenuga
  • Abdul Samad Rabiu
  • Folorunsho Alakija
  • Femi Otedola

Amọ iwadii naa ni ida ọgọta awọn ọmọ Naijiria ni ko ni to miliọnu dọla kan lati na loojọ, eleyii to fi han gbangba iru iya ati isẹ to n jẹ ọpọlọpọ awọn ara orilẹ-ede Naijiria

Bakan naa ni iwadii Oxfam gbe jade ni ọpọlọpọ awọn eniyan ni orilẹ-ede Naijiria ni isẹ ati iya n ba finra.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGọngọ sọ, ẹlẹ́há pàdé àwọn tó lùú ní jìbìtì nílùú Eko lọ́jà Ibadan

Oxfam fi kun wi pe pẹlu u bi Naijiria se jẹ orilẹ-ede to n pese epo rọbi julọ ni ilẹ Afirika, ko ye ki wọn jiya amọ iwa ibajẹ ati jẹgudujẹra lo n fa ifaseyin fun awọn araalu.