Bola Tinubu: Àwọn màlúù dà níbí tí wọ́n ti pa ọmọ Fasoranti?

Bola Tinubu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awuyewuye ló tẹ̀lẹ́ ọrọ ti Asiwaju Bola Ahmed sọ lásìkò tó ń se àbẹ̀wò ibanikẹdun si ile baba Fasọranti ti awọn agbẹbọn pa ọmọ rẹ.

Awọn ọmo Naijiria ti fesi si ọrọ ti Adari ẹgbẹ oselu APC lorilẹ-ede Naijiria, Asiwaju Bola Tinubu to ni kii se Fulani darandaran lo pa ọmọ Baba Fasọranti.

Tinubu lasiko to se abẹwo si adari ẹgbẹ afẹnifẹre, Pa Reuben Fasọranti ti wọn ni awọn agbẹbọn pa ọmọ rẹ abileko Funke Ọlakunrin ni opopona Ọrẹ ni ipinlẹ Ondo sọrọ ibanikẹdun.

Ninu ọrọ rẹ, Tinubu ni ta ni o ri awọn maalu tabi ẹran nibi ti ipaniyan naa ti waye?

Ati wi pe awọn Fulani nikan kọ lo n pa eniyan ni Naijiria pẹlu ibeere pe se Fulani ni Evans ni ti o wa ni atimole fun ẹsun ajinigbe?

Amọ Femi Fani-Kayode lasiko to n fesi lori ikanni Twitter sọ wi pe isọkusọ ni ọrọ ti Asiwaju sọ, a ti pe ọrọ oselu ni Tinubu sọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGọngọ sọ, ẹlẹ́há pàdé àwọn tó lùú ní jìbìtì nílùú Eko lọ́jà Ibadan

Fani Kayode ni ki lo kan Lemọmu p\elu itan aja ni ibeere Tinubu lori Evans ati ọmọ Baba Fasoranti

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria

Bakan naa ni awọn miran ni oro to jade lẹnu Tinubu ko yẹ ko jade lẹnu rẹ gẹgẹ bi asaaju.

Amọ awọn miran sọ wi pe, Tinubu sọrọ gẹgẹ bi adari ẹgbẹ oselu ni, kii se wi pe o se atilẹyin fun ẹya kan yato si omiran.

Awọn miran gboriyin fun Asiwaju pe ko ṣe ẹlẹyamẹya ninu ọrọ rẹ:

Ninu ọrọ awọn miran adura ni Baba Fasoranti nilo ati pe idanwo nla ni eyi jẹ fun Tinubu gẹgẹ bi Asiwaju ati ẹgbẹ APC lapapọ: