Sanwo Olu dá Bello padà; ó yan kọ̀míṣọ́nnà 25 àtàwọn olùbádámọ́ràn

Image copyright @Sanwoolu
Àkọlé àwòrán Sanwo Olu yan kọ̀míṣọ́nnà 25 àtàwọn olùbádámọ́ràn ti wọn yoo jọ ṣiṣẹ

Yatọ si pe gomina Sanwo Olu forukọ awọn Kọmiṣọnna tọ fẹ ba ṣiṣẹ ranṣẹ sile, O tun yan awọn olubadamọran tuntun.

Gomina ipinle Eko, Babajide Sanwo Olu fi orukọ awọn eniyan mẹẹdọgbọn ranṣẹ sile igbimọ aṣofin nipinlẹ Eko.

Igbakeji agbenusọ fun Gomina Sanwo Olu, Gboyega Akosile lo fi atẹjade naa sita pé Sanwo Olu fi ara balẹ woye yan awọn orukọ naa sipo ni.

Awọn orúkọ naa ti Akoṣile ni Sanwo Olu fi iriri wọn yan sipo naa ni wọnyii:

Awọn ti orukọ wọn tun jade lẹyin ti wọn ti sin ipinlẹ Eko tẹlẹ ni Tunji Bello to ti ṣe akọwe ijọba tẹlẹ, Wale Ahmed to ti ṣe kọmiṣọnna tẹlẹ ati Abilekọ Uzamat Akinbile-Yusuf atawọn miran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGovernorship Election Updates: Sanwo-Olu se abẹwo idupẹ si Bọla Tinubu

Gboyega Akosile ni kete ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinle Eko ba ti ṣe ayẹwo to yẹ ni wọn yoo buwọlu u bi o ti yẹ labẹ ofin.

Akosile ni awọn orukọ yii ni ti ipele akọkọ nitori pe iṣẹ ṣi n lọ lọwọ lati yan awọn to ku ti wọn yoo ba Sanwo Olu ṣiṣẹ fun ilọsiwaju ipinlẹ Eko.

Akọsile ṣapejuwe awọn eeyan yii pe ọrọ wọn yoo ye ara wọn fun itẹsiwaju nitori pe awọn ọdọ ti ko tii pé ọmọ ogoji ọdun wa ninu wọn laiyọ obinrin silẹ.