Obasanjo: Ètò ààbò tó mẹ́hẹ lè dá'jà ẹlẹ́yàmẹ̀yà sílẹ̀

Muhammadu Buhari ati Olusegun Obasanjo Image copyright Twitter/Presidency
Àkọlé àwòrán Àjálù ń bọ̀, tí Buhari kò bá ṣàtúnṣe lórí ètò ààbò- Obasanjo

Aarẹ ana orilẹ-ede Naijiria, Olusegun Obasanjo ti kọ lẹta miiran si Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto aabo to mẹhẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Obasanjọ sọrọ ninu lẹta to fi sita lati ọwọ oluranlọwọ pataki lori eto iroyin rẹ, Kehinde Akinyemi pe dugbẹ dugbẹ to n mi loke lori eto aabo, afai-mọ-ko-ma-ja o.

Aarẹ ana Obasanjo fikun ọrọ rẹ pe ọkan oun bajẹ nitori Aarẹ Buhari ti fi awọn ọmọ Naijiria silẹ sọwọ awọn ọdaran afurasi Fulani darandaran ti wọn dabi awọn agbesumọmi Boko Haram.

Obasanjo ẹru n ba oun pe ija ẹlẹyamẹya le bẹ silẹ tawọn ẹya miiran ba kọju ija si awọn Fulani eyi to le buru jai bi ipaniyan to ṣẹlẹ lorilẹ-ede Rwanda.

Aarẹ ana ni ọrọ eto aabo Naijiria ti kọja ohun ti oun le dakẹ le lori nitori ọwọ ti fẹ bọ sori bayii pẹlu aibikita ijọba apapọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Obasanjo ni awọn ara ilu le bẹrẹ si ni maa ṣe ohun to wu wọn ti ijọba ko ba tete fi wọrọkọ ṣada lori eto aabo ni Naijiria.

O fikun ọrọ rẹ pe ikọlu laarin awọn agbẹ ati darandaran di nla nitori ijọba kọkọ fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa.

Obasanjo sọ pe oju ọrun to ṣu dẹẹdẹ yii, ojo iparun, ojo ajalu ati ojo ainiṣọkan ni yoo fi rọ ti ijọba ko ba wa nnkan ṣe si ọrọ eto aabo ni Naijiria.

Obasanjo ni asọyepọ laarin awọn ẹlẹyamẹya lojutuu si ọrọ eto aabo orilẹ-ede Naijiria to mẹhẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Buhari ní àìlera lẹ́mìí, lára, àti lọ́kàn.