Ìdí iṣẹ́ alápatà ni mo ti rí mílíọ̀nù mi àkọ́kọ́ láyé mi - Derin Ẹlẹ́ran
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Iṣẹ́ ìdọ̀tí ni ẹran títá, ṣùgbọ́n nínú ẹ̀gbin lowó wà - Derin Ẹlẹran

Ootọ iṣẹ́ ìdọti ni iṣẹ alapata ṣugbọn èrè wa nibẹ - Derin Ẹlẹran

Aderinsọla Taiwo ni ọdọbinrin alapata ti BBC fọrọwalẹnuwo lori iṣẹ ẹran tita lọna igbalode.

Derin Ẹlẹran ni àpèjá ti ọpọ awọn onibara rẹ maa n pèé.

O ni pataki dida duro lẹnu iṣẹ ara oun lo jẹ ki oun fiṣẹ silẹ lati gbajumọ iṣẹ ẹran tita.

Derin Eleran ṣalaye nipa idojukọ ati ipenija to wa ninu iṣẹ alapata pe ko rọrun rara ṣugbọn inu idọti ni owo wa.

Derin gba awọn ọdọ Naijiria ti wọn ṣi n wa iṣẹ kiri pe ki wọn wo nkan ti awọn le maa ta tabi ṣe ni ọna igbalode.

Derin ni oun n yọ wahala lọrun awọn ti ko ri aaye lọ si ọja ni, eyi dẹ n pese owo fun oun ni èrè.

Ni igbẹyin, Derin gba awọn ọdọ nimọran lati ma tiju iṣẹ wọn ki ebi ma baa pa wọn.

O ni afojusun oun ni lati ni ọgba ẹran maalu, ogunfe ati agbo ti ara oun.

Derin sọ pataki nini ọyaya pẹlu iṣẹ ti eeyan ba n ṣe.