Ilupeju Killing: Àṣìta ìbọn pa ẹnìkan lásìkò t'ọ́lọ́pàá kojú adigunjalè

SARS Image copyright POLICENG_PCRRU/TWITTER

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ibọn pa arakunrin kan lasiko ti awọn oṣiṣẹ ajọ ọlọpaa SARS ati awọn janduku kan koju ara wọn lagbegbe Ilupeju nipinlẹ naa.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Bala Elkana, ninu atẹjade kan sọ pe iṣẹlẹ naa waye lasiko ti Ọga ọlọpaa kan, Inspẹkitọ Mohammed Akeem ati awọn ọmọ ikọ rẹ n mu olori ikọ janduku kan, Ikechukwu Monye lọ si ibi ti oun ati ikọ rẹ ma n ko awọn nkan ija oloro wọn pamọ si ko to di pe awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ pade wọn lọna ni adugbo Ajisegiri, l'agbegbe Ilupeju.

"Awọn janduku naa bẹrẹ si ni yinbọn, ibọn wọn lo si ba arakunrin kan to n kọja lọ."

Elkana sọ pe ikọ janduku naa ti ṣe ọpọlọpọ idigunjale ni Ilupeju ati awọn agbegbe to wa ni tosi rẹ.

Adájọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi ọlọ́pàá tó lọ́wọ́ nínú ikú Kolade Johnson sí àhámọ́

'Àwọn SARS ló yìnbọn pa ìyá mi'

"Ileeṣẹ ọlọpaa ti n wa wọn tipẹ fun ẹsun pe wọn pa eniyan mẹfa lasiko idigunjale mẹta ọtọọtọ ti wọn ṣe.

Ṣaaju ni aworan oloogbe kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Francis jade si ori ayelujara. L'ẹgbẹ aworan oloogbe naa ni awọn nkan bi igbalẹ, ike ipọnmi wa.

Awọn Iroyin ti ẹ le nifẹ si

Awọn kan lori ayelujara sọ pe agbalẹ ni ọkunrin naa jẹ ni adugbo ibi ti iṣẹlẹ yii ti waye, ati pe ibọn awọn ọlọpaa SARS to n le awọn to n mu igbo lo pa a.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọ si bayii fun ayẹwo.