Dálémoṣú ni mí ṣùgbọ́n ó ni ìdí - Adaku inú eré Jẹnifa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Funke Akindele jẹ àkàndá ẹ̀dá - Adaku

Kìí ṣe gbogbo Dalemoṣu lo n ṣe aṣẹwo - Adaku

Omotunde Adebowale ni orukọ abisọ ti oṣere to tun jẹ sọrọsọrọ ti igba oju mọ ti wọn n pe ni Adaku ninu eré Jẹnifa.

BBC Yorùbá gbalejo Adaku ninu ile iṣẹ wa nibi to ti sọrọ ni kikun lori ikọraẹnisilẹ.

Adaku ni ẹnu araye lẹbọ ninu ọrọ igbeyawo nitori wọn a ni ki lode too ṣe sọrọ sita tabi o kuku ti n sọrọ ju.

Oṣere yii royin oun ti oju obinrin to ti kọ ọkọ silẹ n ri lawujọ Yoruba.

O ni ọpọ ninu awọn ọrẹ ni ọkọ wọn ni ki wọn yẹra fun mi bẹẹ ko si ẹni to wù láti dalemoṣu laye.

Adaku ni awọn eeyan maa n sọ pe awọn ọmọ obinrin ti ko si nile ọkọ ko le yanju ṣugbọn Olorun ju ẹda lọ.

O ni oju ẹni to kọ ọkọ rẹ silẹ n ri to!

Adaku ṣalaye iru eeyan ti Funkẹ Akindele jẹ pẹ kii fi iṣẹ rẹ ṣere koda a le sọ pe ó burú.