Building Collapsed: O kéré tán, ènìyàn 10 ló ti jáláìsí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilé tó wó ọ̀hún

Image copyright other
Àkọlé àwòrán Building Collapsed: O kéré tán, ènìyàn 5 ló ti jáláìsí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilé tó wó ọ̀hún

O kéré tán, ènìyàn 5 ló ti jáláìsí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilé tó wó ọ̀hún.

Ajọ alagbelebu pupa to n mojuto eto didoola ẹmi awọn eniyan to ri sinu ile to wo ni Jos ni oku ti wọn ri ti pọ sii.

Won ṣalaye fun akọroyin BBC pe awọn ti yọ oku mọkanla bayii ninu ile alaja mẹta ọhun.

Awọn agbofinro ni ẹkun Jos ni awọn ko tii le sọ ohun to ṣokunfa ile to wo naa.

Ajọ NEMA to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria naa ni gbogbo iṣẹ lawón n ṣe lati wa gbogbo awọn to ri sinu ile to wo naa.

Agbẹnusọ awọn agbofinro ni ẹkun yii, Yyopev Mathias ni nkan bii aago mẹrin irọle ana ni awọn gba ipe lori ile to wo naa.

O ni awọn ti wọn ti ri yọ laaye ni wọn ti ko lọ sile iwosan Plateaus Specialist ati Bringham University Hospital.

Ki lo ti ṣẹlẹ tẹlẹ ni Jos?

Image copyright lasema
Àkọlé àwòrán Iṣẹ n tẹsiwaju lọjọ Iṣẹgun

Ile alaja mẹta lo deede dà wó ni ilu Jos ni ipinlẹ Plateau ni ariwa Naijiria.

Iroyin ni o kere tan awọn marun un ni wọn ti dologbe nibi iṣẹlẹ ọhun nigba ti ọpọlọpọ si farapa.

Akoroyin BBC ni ọpọlọpọ wakati ni awọn oṣiṣẹ ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri àti awọn ara ilu fi ṣiṣẹ lati doola ẹmi awọn to ri sinu ile to da wo naa.

Wọn ti gbe awọn ti wọn ti ri lọ sile iwosan bi wọn ṣe yọ wọn.

Ẹbi ta ni ti ile bá dà wó?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOnimọ nipa ile kikọ sọwipe ijọba nilo awọn onimọ nipa owo ori ile

Akoroyin BBC ni ajọ alagbelebu pupa to n ṣiṣẹ nibẹ ti fidiẹ mulẹ pe Baba onile naa ati awọn ọmọ rẹ meji wa lara awọn ti wọn ti ri oku wọn yọ nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni to ni ile iwe sare lati doola awọn akẹkọ ni ile wolu

Ko si ẹni to mọ iye awọn eniyan to ṣi ku sinu àwótì ile alaja mẹta naa ni eyi ti iṣẹ tun ti bẹrẹ ni aarọ kutu oni.

Ile alaja mẹta yii ni awọn iyara aladagbe to pọ ati ọpọlọpọ ile itaja ti wọn kọ papaọ ni aarin gbungbun Jos.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlórí Ọ̀dọ́ l'Ondo ní oníkálùkù yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní jà fúnra wọn