Seyi Makinde: Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo kéde dúkìá tó tó #48bn

Image copyright @Seyi
Àkọlé àwòrán A ju ara wa lọ ijakadi kọ

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kede dukia rẹ eyi to to ogoji biliọnu naira.

Ṣaaju idibo lo ti kọkọ kede pe oun a gbe igbesẹ yii ti oun ba wọle ni eyi to ti muṣẹ bayii.

Lati igba to ti ṣe ikede yii ni ero awọn ọmọ Naijiria ti ṣotọọtọ lori ikede naa.

Ọpọlọpọ lo ti ki Seyi Makinde fun iwa akin to hu nipa mimu ileri rẹ ṣe. Eyi kò yọ oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar silẹ

Bẹẹ naa ni awọn kan n ṣakawe ohun ini ti Seyi kede pẹlu eyi ti aarẹ Buhari kede pe o jẹ dukia oun.

Eyi tun ti jẹ ki awọn kan maa beere orisun owo gomina Seyi Makinde ni bi eto ọrọ aje ṣe ri lasiko yii.

Image copyright @Seyi
Àkọlé àwòrán Kini orisun owo Seyi Makinde ni ibeere awọn kan?

Koda loju òpó BBC Yoruba gan an, awọn eeyan mi n gbadura ki ori awọn naa di apesin bii ti Makinde.

Àkọlé àwòrán Oro wa ko kuku dọgba ni adura ọpọ ero

Ohun to kọ iwaju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomii, awọn miran ni Seyi Makinde lo kọkọ gbe iru igbesẹ bayii ninu itan ipinlẹ Oyo pe:

Awon kan tun ni o ti ṣe ju ohun ti awọn to n gbogunti iwa ibajẹ miran ko ṣe paapaa.

Image copyright Facebook/Seyi Makinde
Àkọlé àwòrán Seyi Makinde: Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo kéde dúkìá tó tó #48bn

Gómìnà Makinde ìpínlẹ̀ Oyo kéde dúkìá tó tó #48bn

Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ti kede dukia to to biliọnu mejidinlaadọta naira gẹgẹ bi ohun ini rẹ.

O ni eyi jẹ imuṣẹ ileri t'oun ṣe lasiko ipolongo idibo k'oun to di gomina ipinlẹ Oyo.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin si gomina, Ọgbẹni Taiwo Adisa fi sita, Gomina Makinde ni owo to le ni igba miliọnu nairia nipamọ ko to gori oye gẹgẹ bii gomina.

Bakan naa, Makinde ni ẹgbẹrun un lọna ọgbọn owo dọla titi di ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu karun un nile ifowopamọ si.

Gomina Makinde tun ni dukia to to miliọnu lọna ẹgbẹrun mẹrin o le nirinwo owo dọla nipamọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMo fi iṣẹ́ Banki silẹ̀ lọ bẹ̀rẹ̀ alápatà - Derin

Ninu ikede dukia rẹ, Gomina Makinde nile mẹsan an ni Naijiria, meji l'Amẹrika pẹlu ẹyọ kan lorilẹ-ede South Africa.

Amọ, oun ati iyawo rẹ ni wọn jọ ni ọkan ninu awọn dukia rẹ to wa l'Amẹrika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKi ni o mọ to n jẹ owo iranwọ epo?

Wọnyi ni awọn ile iṣẹ ti gomina Makinde ni ko to di gomina ipinlẹ Oyo- Makon Engineering & Technical Services Limited, Energy Traders & Technical Services Limited, Makon Oil & Gas Limited, Makon Group Limited, Makon Construction Limited & Makon Power System Limited ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIbikunle Amosun: Owo adani ni'ṣẹ ẹran dida, ko kan ijọba

Gomina Makinde rọ awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ lati ṣe bakan naa

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEjo abami to n mu owo ni ajọ Jambu