Dino Melaye: Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá yóò ṣèwádìí fídíò tí Dino ti ń náwó fún olórin kan

Sẹnẹtọ Dino Melaye loju agbo Image copyright Instagram/dinomelaye
Àkọlé àwòrán A ó gbé'gbésẹ̀ lẹ́yìn ìwádìí fídíò tí Dino ti ń náwó fún Ayefẹlẹ- Ọlọ́pàá

Ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn yoo ṣe iwadii fọnran kan to ṣafihan bi Sẹnẹtọ Dino Melaye ti n fi owo mọ olorin gbajugbaja kan lori loju agbo.

Igbakeji alukoro fun ile iṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọgbẹni Adeniran Aremu to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ile iṣẹ ọlọpaa yoo gbe igbesẹ to ba yẹ lẹyin to ba pari iṣẹ iwadi lori fọnran ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDino Melaye nánwó fún Ayefẹlẹ lójú agbo

Ọgbẹni Aremu sọ pe o ṣe pataki lati wo fọnran finifini nitori ọpọ eeyan lo n fi ọgbọn alumọnkọrọi gbe fidio jade lori ayelujara.

O fikun ọrọ rẹ pe ile iṣẹ ọlọpaa yoo ṣa ipa rẹ lati mọ orisun fidio ti Sẹnẹtọ Dino Melaye ti nanwo loju agbo naa.

Bọndu owo nla lo wa lọwọ Ọgbẹni Dino ninu eyi ti o ti n na olorin lowo nibi inanwo oku iya rẹ nipinlẹ Kogi ninu fidio naa

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAwọn ọdọ Ondo fẹ̀họ́nù hàn lórí ìṣekúpani Funke Olakunrin

Ẹwẹ, ọjọ Abamẹta to kọ ja ni ọkan lara awọn ọga agba nile ifowopamọ Naijiria (CBN), Isaac Okorafor sọ pe ile ifowopamọ naa ti ṣetan lati fọwọ ofin mu ẹnikẹni to ba n ba owo naira jẹ nipa fifi ṣe imọri loju agbo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMo fi iṣẹ́ Banki silẹ̀ lọ bẹ̀rẹ̀ alápatà - Derin