Dino Melaye nánwó fún Ayefẹlẹ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Dino Melaye nánwó fún Ayefẹlẹ lójú agbo

Ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn yoo ṣe iwadi fọnran kan to ṣafihan bi Sẹnẹtọ Dino Melaye ti n fi owo mọ olorin Yinka Ayefẹlẹ lori loju agbo.

Igbakeji alukoro fun ile iṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọgbẹni Adeniran Aremu to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ile iṣẹ ọlọpaa yoo gbe igbesẹ to ba yẹ lẹyin to pari iṣẹ iwadi lori fọnran ọhun.

Ọgbẹni Aremu sọ pe o ṣe pataki lati wo fọnran finifini nitori ọpọ eeyan lo n fi ọgbọn alumọnkọrọi gbe fidio jade lori ayelujara.