COZA: Lẹ́yìn ìwadìí PFN ni CAN tó leè sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Fatoyinbo

Ami idanimọ CAN/Biodun Fatoyinbo

Oríṣun àwòrán, CAN/Fatoyinbo

Apapọ ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, ti sọ pe oun ko mọ nkankan nipa bi awọn kan ṣe ṣe abẹwo a n bẹ lẹyin rẹ si COZA.

Lọjọ Aiku to kọja ni awọn alufaa naa ṣe abẹwo ọhun si ijọ Commonwealth of Zion Assembly.

Ninu atẹjade kan ti Oludari Apapọ fun eto ofin ati ikede fun CAN, Ajihinrere Kwamkur Samuel Vondip fi sita lọjọ Aje lo ti ni ọrọ ko ri bẹẹ.

O ni ẹgbẹ CAN sọ pe oun ko lọwọ si abẹwo ọhun ati fidio rẹ to gba ori ayelujara.

Àkọlé fídíò,

COZA: Ọpọ èrò ló jáde ṣe lòdì sí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ Fatoyinbo

Bakan naa ni Kwankur sọ pe awọn pasitọ to wa ninu fidio naa lọ sile ijọsin COZA latinu ifẹ ọkan wọn ni.

''Eyi ni lati sọ fun gbogbo eniyan pe wọn ti pe akiyesi Aarẹ ẹgbẹ CAN, Ẹni Ọwọ Samson O.A Ayokunle si iroyin ati fidio kan lori ayelujara pe ẹgbẹ CAN ran awọn aṣoju lọ sinu ijọ pe awọn ṣatilẹyin fun Pasitọ Agba ijọ naa, Biodun Fatoyinbo, ti wọn fi ẹsun ifipabanilopọ kan."

O ni "Atẹjade yii wa lati jẹ ki gbogbo awọn olori ẹsin Kristiẹni, araalu, ati awọn to fẹran otitọ, mọ pe ẹgbẹ CAN tabi Aarẹ CAN ko fi ọwọ si tabi mọ nkankan nipa abẹwo atilẹyin naa."

Ẹgbẹ CAN sọ pe oun ko ti i yi ohun pada lori ọrọ ti oun sọ tẹlẹ pe lootọ ni awọn ko faramọ iwa ibajẹ kankan lati ibikibi, ṣugbọn oun ti fi aaye silẹ fun ẹgbẹ Ijọ Ẹmi Mimọ, PFN ti ijọ COZA n ṣe, lati ṣewadi ẹsun ifipabanilopọ naa, ko si jabọ fun ẹgbẹ CAN.

'' A le fi idi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ PFN ti bẹrẹ iwadii, abọ iwadii na yoo si jade sita titi ọsẹ meji si asiko yii. A ko si ni ṣe idiwọ fun ijiya to ba tọ si ẹnikẹni to ba hu iwqa ti ko tọ ọ.

Àkọlé fídíò,

Funke Akindele jẹ àkàndá ẹ̀dá - Adaku

Aarẹ ẹgbẹ CAN, Ẹni Ọwọ Samson O.A Ayokunle, sọ fun BBC Yoruba pe ẹgbẹ CAN ko le ṣe atilẹyin fun Fatotinbo tabi Busola lai jẹ pe ẹgbẹ PFN ti CAN fun ni aṣẹ lati ṣe iwadii ọrọ naa ba jabọ.

" A gbọdọ tẹle ilana to yẹ, ao si ri i pe a tẹle nitori ki otitọ le jọba.''

Ọjọ Aiku ni fidio kan gba ori ayelujara, to si ṣafihan awọn pasitọ kan ti wọn ni awọn jẹ aṣoju ẹgbẹ CAN ẹka ilu Abuja, lẹnu abẹwo lọ si olu ijọ COZA, to wa nilu Abuja.

Nibẹ ni wọn ti sọ fun Pasitọ Biodun fatoyinbo pe digbi ni awọn wa lẹyin rẹ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.

Fidio naa mu ki ọpọlọpọ ọmọ Naijiria o koro oju si ẹgbẹ CAN.

Oṣu Kẹfa ni iyawo gbaju-gbaja akọrin, Timi Dakolo, Busola Dakolo, ninu ifọrọwanilẹnuwo kan fi ẹsun kan Fatoyinbo pe o fi ipa ba oun lo pọ lẹẹmeji ọtọọtọ ki oun to o pe ẹni ogun ọdun.

Oríṣun àwòrán, Biodun Fatoyinbo

Àkọlé àwòrán,

Iyawo gbaju-gbaja akọrin, Timi Dakolo, Busola Dakolo, fi ẹsun kan Fatoyinbo pe o fi ipa ba oun lo pọ lẹẹmeji ọtọọtọ ki oun to o pe ẹni ogun ọdun.

Ẹsun naa fa awuyewuye l'oriṣiriṣi jakejado orilẹede Naijiria. Awọn kan tilẹ ṣe iwọde lọ si ẹka ileejọsin COZA nilu Abuja ati Eko, pe ki Biodun Fatoyinbo kuro ni ipo Pasitọ ninu ijọ naa.

Lẹyin eyi ni Fatoyinbo kede pe oun ti yẹba naa. Ṣaaju lo ti fesi si ẹsun ti Dakolo fi kan an pe oun ko fi ipa ba ẹnikẹni lo pọ ri.