Fasoranti: Ẹ̀mí àwọ̀n darandaran Fulani kò dè mọ́ ní Gúsù Nàìjíríà, kí wọ́n padà sókè ọya ní kíákíá

daradaran fulani kan ati agbo ẹran rẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ àgbà òkè ọya Nàìjíríà, NEF ni ọrọ idunkukulaja to n waye lẹnu awọn agba iha Gusu Naijiria lo n mu ki aṣẹ naa waye

Hmmm... a ma n pe ọrọ yii lowe o ma n laro ninu.

Lori ọrọ ipenija aabo to n ranju mọọ mọ Naijiria yii ni ẹgbẹ awọn agba loke ọya Naijiria, Northern Elders Forum (NEF) ati agbarijọpọ awọn ẹgbẹ kan nibẹ ti ni kawọn darandaran fulani o ṣẹri wale si apa oke ọya.

Wọn ni oke ọya ni awọn ti lee fi ọwọ sọya lori ẹmi wọn ati maluu wọn.

Ẹgbẹ awọn agba apa oke Ọya orilẹ-ede Naijiria naa ni ilu ogun tawọn kan n lu lapa guusu ilẹ yii lori wọn n kọ awọn lominu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Fulani Ilorin l'ọkọ mi'

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn agbebọn kan ti ọpọ furasi gẹgẹ bi awọn darandaran Fulani pa arabinrin Funkẹ Olakunrin.

Eni to jẹ ọmọ ọkan lara awọn agba to lorukọ nilẹ Yoruba, Rueben Faṣọranti.

Eyi si ti fa ọpọ ipe da ina ogun, da ina ọtẹ lataọdọ awọn eekan kan ni ilẹ Yoruba lori lemọlemọ iṣẹlẹ ijinigbe ati igbenipa to n waye lapa iwọ oorun guusu orilẹ-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYomi Lanso wipe ka jọ gbadun laye

Ninu ọrọ ti wọn ba awọn oniroyin sọ, Ọjọgbọn Ango Abdullahi to jẹ alaga ẹgbẹ agba oke ọya Naijiria ni nibi ti ọrọ de duro bayii, ko daju pe ẹmi awọn darandaran Fulani de mọ ni apa guusu orilẹ-ede Naijiria ti wọn wa.

O ni lootọ ni iṣọkan Naijiria jẹ awọn logun ṣugbọn ko de ibi ati fi ẹmi ẹya kan ra a pada.

O wa pe fun idasilẹ igbimọ oluwadi kan ti yoo ṣe ọfin toto ọwọja wahala awọn darandaran ati agbẹ olohun ọgbin ki wọn le e san owo ofo to ṣẹ koowa fun un.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlórí Ọ̀dọ́ l'Ondo ní oníkálùkù yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní jà fúnra wọn