Fulani Heardsmen: Afenifere ní àṣẹ tó bá wu àwọn àgbààgbà agbègbè àríwá Nàìjíríà kí wọ́n pa

Fulani Heardsmen: Afenifere ní àṣẹ tó bá wu àwọn àgbààgbà agbègbè àríwá Nàìjíríà kí wọ́n pa

Afenifere ní 'Rakatia' ni ìpè àwọn àgbààgbà agbègbè àríwá Nàìjíríà tó ní kawọn darandaran ó padà wálé

Ẹgbẹ awọn agba loke ọya Naijiria, Northern Elders Forum (NEF) atawọn agbarijọpọ ẹgbẹ kan nibẹ paṣẹ fun awọn darandaran fulani ti wọn wa ni apa guusu orilẹ-ede Naijiria lati tete dari pada si oke ọya.

Wọn ni ki wọn pada sile pẹlu awọn agbo ẹran wọn nitori ibẹru fun aabo ẹmi awọn ati ẹran wọn.

Nibayii, ẹgbẹ afẹnifẹre ilẹ Yoruba naa ti da wọn lohun pe, eyi ko lee tu irun kan lara iduro ṣinṣin ẹya Yoruba.

Ati pe koko ti awọn mọ ni pe ifẹmiṣofo ti awọn agbebọn ti ọpọ fura si pe wọn jẹ darndaran fulani n ṣe nilẹ Yoruba to gẹ.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Alagba Yinka Odumakin ṣalaye pe Yoruba ko sọ pe gbogbo Fulani lo n gbẹmi awọn eeyan nilẹ Yoruba.

Ṣugbọn sibẹ ojuṣe awọn to jẹ ẹni rere ninu wọn ati ijọba pẹlu ni lati hu awọn oniṣẹ ibi aarin wọn jade, bi bẹẹ kọ, ọrọ ọhun ti di má fi oko mi ṣe aala, eleyi to jẹ pe ọjọ kan bayii leeyan n kọọ.

Ọgbẹni Odumakin ni bi ẹmi eeyan ko ba jọ awọn oniṣẹ laabi aarin awọn darandaran Fulani naa loju ki wọn ara wọn naa ṣodiwọn.

Bakan naa lo sọ pe ọna ati da wahala silẹ lorilẹ-ede Naijiria ni ati pe ilẹ Yoruba ko ni gba a.

Nigba ti BBC News Yoruba tun gbiyanju ati gbọ tẹnu awọn gomina, paapaa nipasẹ ẹni to jẹ alaga ajọ awọn gomina lorilẹ-ede Naijiria, (Governors forum) Gomina Kayọde Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti, agbẹnusọ rẹ, to ba wa sọrọ lori tẹlifoonu ṣalaye pe, akọkọ igba kọ niyi ti ẹgbẹ kan yoo dide nihin tabi lọhun lati gbe aṣẹ kalẹ to si jẹ pe asan lasan ni.

O ni ọgbọn ati da wahala silẹ lorilẹede Naijiria ni ipe yii ati pe ko si idi fun awọn ọmọ orilẹede yii lati ko aya soke lori rẹ.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ni wọn igba ti ko tii si darandaran fulani kan to tii maa di igba ati agbọn rẹ kuro lapa guusu gba ọna ariwa orilẹ-ede Naijiria lọ, eremọde lasan ni ipe naa.