Báwo ni Yorùbá ṣe ń kí onídìri?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ti o bá dá ara ẹ lójú, ki ẹni tó n ṣe irun kí n gbọ́?

Ẹ wo oriṣii ìkíni ti awọn èèyàn fún onidiri.

Ẹyin ọmọ Yoruba atata. O ya, iṣẹ kàn yín, bawo ni ogidi ọmọ Yoruba ṣe n ki onidiri?

E ku oge; E ku ẹwà, ẹ ku iṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni a n gbọ,

Wọn gba a, ṣugbọn o ni ijinlẹ ikini fun awọn ti wọn n di irun eeyan nilẹ Yoruba yatọ si eyi.

"Ojú gbooro o" ni ogidi ikini fun onidiri eyi ti awọn kan ni o tumọ si pe ojú a ríran la ilà irun naa daadaa.

Wọn ni ila irun naa a gbooro pe ila irun naa kò ni wọ́.

" Òòyà á yà á o" ni idahun ti ẹni to n ṣe irun maa fi dahun ti wọn ba ki i tan.

Awọn kan ni eyi tumọ si pe ooya (cutting comb) ti awọn iya wa fi n yarun laye atijọ a ya irun naa daadaa ni.

Related Topics