Mercy Aigbe: Iṣẹ́ ọwọ́ mi ni mó n jẹ, gómìnà àbi ààrẹ kò gbọ́ bùkátà mi

mercy aigbe Image copyright Mercy aigbe

Gbaju-gbaja oṣere tiata, Mercy Aigbe ti sọrọ sita lati wẹ ara a rẹ mọ, ninu ahesọ ọrọ kan to n lọ nigboro pe 'ọkunrin lo fi n gbe bukaata ara rẹ.'

Se bi ogun ẹni ba da ni loju, aa fi gbari ni. Ninu ọrọ kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ, Mercy sọ pe isẹ́ loun n se, ki oun to ri taje se.

''Mo n gbiyanju aje bayii, ko sẹni to ri mi, amọ nigba to ba ya, ti mo gbe aworan ọpọ ile mi sori ayelujara, wọ̀n yoo la ẹnu ẹlẹya wọn pe ‘gomina kan‘ abi ‘aarẹ kan’ lo ra ile awosifila, ọpọ ọkọ ayọkẹlẹ ati awọn ilegbe fun mi."

"Wọn yoo maa fi ẹnu tẹnbẹlu isẹ asekara mi...adura mi ni pe, baba, gbogbo ẹnu esu ti ko wulo, to fẹ maa tabuku ibukun rẹ ninu aye mi, ki ina ẹmi mimọ lọ kọlu wọn, ki wọn si maa sisẹ lai ni akojọ ni orukọ Jesu."

"To ba jẹ iwọ ni adura yii wa fun, ko yara tete wa ọ ri ni kiamọsa."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdun 2018 ni iroyin gba igboro pe, gomina ipinlẹ kan nilẹ Yoruba to jẹ ololufẹ ikọkọ Mercy, lo ra ile ti oṣere tiata naa fi aworan rẹ sita, fun.